Ayeye odun Eyo atawon asa nla mii-in yoo pada sipinle-Ogun apo Abiodun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 26 May 2019

Ayeye odun Eyo atawon asa nla mii-in yoo pada sipinle-Ogun apo Abiodun
Gomina ipinle Ogun ti won sese dibo yan, Dapo Abiodun ti muu da gbogbo omo ipinle naa loju pe odun Eyo ti won maa n se ni Ekoo, ti won ti mu ni pataki lagbaye yoo pada sipinle Ogun, nitori Iperu gan-an ni won ti bere e ati pe isakoso ijoba oun yoo ri pe won so ipinle naa di ile isinmi igbafe ti yoo se dun wo loju, tawon orileede mii in yoo maa wa.

Gbongan Cultura  Center, niluu Abeokuta lo ti soro yii ni ale ojo Abameta, Satide, lakooko ti won se asale asa fun ti ayeye igbejoba kale ti yoo waye lojo kokandinlogbon, osu yii.

O fi iduunu e han bawon okan-o- jokan awon ojogbon nidii ise asa ati ise se pejupese sibi eto naa, pelu bo se ri awon eeyan bii Jimi Solanke, Ogungbe, Ogogo atawon eeyan mii in nijoko. O wa seleri lati pese abule tiata nibi tawon nnkan asa yoo wa nibe, ti won yoo si di oun amulo.


Dapo Abiodun tun salaye pe oun mo pe Olorun febun jinki awon omo ipinle yii nipa asa ati ise, ti won si ti kopa lorisirisi nipase amuludun, o wa seleri pe oun ko nii je kawon ebun naa loo lasan, ijoba oun yoo si tun samulo won fun idagbasoke  lati mu igbega bawon, ti yoo si tun je ki owo maa tipase won wole fun ijoba.


Okunrin naa so pe ayeye odun Eyo to di nnkan ti gbogbo aye tewogba bayii lagbaye Iperu, nipinle Ogun ni won ti bere e. O wa ni ijoba oun yoo maa se ayeye naa atawon asa nla mii in nipinle naa.


Nigba toun naa soro nibi asale asa naa, Oloye Olusegun Osoba, gomina tele nipinle Ogun, fi idunnu e han fun eto ti won se naa, eyi to so pe o mu ogbon dani. O so pe oun to dara ni lati maa saponle ati mo riri awon eeyan ti won ti kopa pataki fun idagbasoke ipinle.
Nibi tinu Osoba dun de lojo naa, ko mogba toun gun ori itage to loo n bawon jo lori itage, o wa daa labaa pe eni to sagbekale orin ipinle Ogun iyen Oloogbe Dayo Dedeke gbodo ni nnkan ti won yoo se fun un nipinle naa.


Gbogbo awon to wa nibe lojo naa ni won da laraya pelu orisirisi eto orin, ere ori itage atawon nnkan mii in ti won se lojo naa.Ola to dara ni won pe akole ere naa.

Asale asa naa ni Onarebu Muyiwa Oladapo je alaga igbimo e nigba ti Yemi Olanrewaju ati Jimmy Solanke je igbakeji e.


No comments:

Post a Comment

Pages