Loni in, ojo
Abameta, Satide, ni ayeye ifilole ijo Olorun ati gbigba ami ororo Ojise Olorun
E A Oluga, gege bi oludasile ijo tuntun waye ni soosi Kerubu ati Serafu, Agbala
Jesu, to wa ni Abule- Oloni, niluu Abeokuta.
Nibi eto naa
lawon ojise Olorun ninu Ijo Kerubu ati
Serafu ti pejo po fun ayeye nla naa to waye ti won sib a oludasile ijo
tuntun naa yo fun oore ti Olorun se fun un.
Bo tile je
pe ko tii pe ti won bere isin ninu ijo naa sugbon ayeye to waye loni in yii lo je
ki won fidi ijo naa mule daadaa tawon agbagba ijo to pejupese nibe, ti won si fun Alagba Oluga
niwe eri oludasile ijo tuntun, leyin ti won tit a ami ororo lee lori.
Ninu oro
oniwasu ojo naa, Alagba Olagoke lo ti ro oludasile ijo tuntun naa lati te
siwaju nidii ise iranse to gba, o si so fun un pe orisirisi egbin ni yoo maa ba
pade sugbon ko ma se weyin rara.
Lara awon
agbaagba ijo to wa nibe lojo naa ni Alagba Olabinke, Alagba Odedairo, Alagba
Biyi Ogundiimu atawon eeyan Olorun mii in.
Orisirisii
orin emi lawon egbe akorin to wa nibe fid
a awon eeyan lara ya. Owo otun Olorun ni won fi se akori ifilole ijo tuntun naa,
eyi ti won mu jade ninu iwe Orin Dafidi ori kejidinlogofa ese kerindinlogun.
No comments:
Post a Comment