Ojo
manigbagbe lojo Isegun, Tusidee, ose yii je fun gbajugbaja to n seto oloyinbo
nni How Una Dey iyen Ogbeni Kehinde
Soaga topo awon ololufe e mo si Son of the soil fun ti ayeye odun keje to ti
maa n seto naa lori telifisan ni OGTV to se.
Ayeye ohun
to waye ni gbongan Prodence, Lemme, niluu Abeokuta, nibi tawon osere oloyinbo
ati ti Yoruba ti peju pese lati sayesi okunrin naa.
Eto to maa n
waye lori telifisan naa ni Kehinde Soaga ati Afeez Ayetoro topo mo si Simply
Saka maa n se ni gbogbo ojo Abameta, Satide, bere ni deede aago mesan an abo si
mewaa abo aaro.
Opo awon eeyan
ni won ti gba lalejo ninu eto pijin naa,
ninu oro
Kehinde Soaga nigba to n ki awon eeyan kaabo, lo ti so pe awon
sagbekale eto naa fun igbaladun awon araalu, o ni bo tile je pe awon kan so pe
eto Amosun ni sugbon o ni ko ri bee rara.
O ni eto naa
ko lowo ijoba ninu rara sugbon tijoba baa se daadaa awon ni lati so fun araalu. O ni idi tawon fi se eto naa
ni pijin ni pe ede yii lo pa gbogbo eeyan po lorileede yii, nitori ko seni ti
ki i so, o wa dupe lowo Olorun pe o gba gbogbo ogo latigba tawon ti bere, tawon
ko si figba kankan rewesi.
Lara awon nnkan
ti won tun se lojo naa ni ni fi fawon eeyan ni awoodu paapaa julo awon to maa n da si eto naa daadaa, bee ni won tun
fun akowe ijoba nipinle Ogun, Taiwo Adeoluwa ati Gomina Ibikunle Amosun.
Ninu oro e,
Taiwo Adeoluwa, fi idunnu e han lori ayeye odun keje ti won se naa, o ni bo
tile je pe oun ki i gbele sugbon akoko toun ba wa nile, oun maa n wo eto naa.
O wa
gboriyin fawon to n seto naa pelu ise opolo ti won se. bee naa lo tun lo akoko
naa lati fi dupe lowo awon osere fun ifowosowopo won pelu ijoba lati bi odun
mejo seyin.
No comments:
Post a Comment