Orin ope
lo gbenu awon ero inu moto ti ori ko yo ninu ijanba moto kan to waye losan an
yii ni Akinale, loju ona Abeokuta si Ifo.
Gege bi a
se gbo, ojo kan to ro ti omi gba gbogbo oju titi naa lo sokunfa ijanba naa.
Iwadii fi ye wa pe ere asapajude ti dereba moto naa n sa bo lo sokunfa, to fi
ko si omi naa lojiji.
Bi won lo
se wonu omi naa ni agbara e ko gbe e mo, eyi to mu ki moto naa takiti lojiji,
to si dabuu saarin ona, se lawon to wa nitosi sare si won, ti won si n yo awon
eeyan jade.
Bo tile je
pe ko seni to ba isele naa lo sugbon awon eeyan farapa yannayanna sugbon ti omo
kekere kan lo lagbara ju, se ni won sare gbe omo naa loo si osibitu.
Ibadan ni
won so pe moto naa ti n bo loo si ifo, iyalenu lo si je pe o ku die ki won de
Ifo nijanba naa waye.
No comments:
Post a Comment