Soosi St Annes Catholic, to wa ni Ibara, niluu Abeokta, ko gbero fawon
osise alabo tijoba ipinle Ogun sese sagbekale iyen So Safe Corps lojo Aiku,
Sannde, nigba ti won wa fun isin idupe pataki.
Oga agba fun ileese naa, Soji Ganzallo, lo saaju awon eeyan e wa sibi isin idupe naa fun
oore nla ti Olorun se fun lati je ki ileeese to ti n je fijilate nipinle Ogun
yi oruko pada di eyi ti won n je bayii.
Ninu oro oniwaasu lojo naa, Eni owo Odetoyin gboriyin fun ileese
So Safe Corps fun awon aforiti ti won ti la koja ati igboya ti won ni lati maa
fi sise ti won n se naa. O ni igbagbo ti won ni ninu Olorun lo je ki won
saseyori ti won se naa.
O wa ro awon osise alabo naa lati tubo nigbekele ninu Olorun ati
lati maa fi se akoko ninu gbogbo nnkan ti won ba n se. O wa gbadura pe ki Olorun
maa saaju won nigbogbo igba
Leyin naa ni won gbadura fun gbogbo awon osise alabo naa pe ki isokan ati ife maa ba won lo Ki Olorun fun won lokun ati agbara lati le dojuko awon
ipenija ti won ba n ba pade.,
No comments:
Post a Comment