Fon-fon-fon logba ile Salvador Tower, to wa ni Game- Village,
niluu Eko kun lojo Aiku, Sannde, ana, nibi ti won ti si mosalasi tuntun
olowo-nla ti agba oselu, to tun je elesin nni Onarebu Moshood Salvador ko si
ogba ile naa, lati le kawon musulumi to n gbe lagbegbe naa lati maa josin.
Won sayeye naa mo ti idanilekoo olodoodun lakooko awe ti okunrin
naa maa n se, nibi to ti maa n febun tore fawon araalu.
Nibe lawon eeyan jakanjakan olori elesin atawon agba oselu ti
peju pese, lara awon to wa nibe ni Alaaji Tunde Balogun to je alaga fegbe oselu
APC nipinle Eko, Seneto Anthony Adefuye atawon eeyan mii in.
Nigba to n bawon eeyan soro nibi ayeye naa, Salvador ro awon
asaaju lati lo akoko awe ti won wa yii lati fi sunmo awon eeyan lati se nnkan
ti won ba n fe. O ni lati maa ferin senu awon to n fe iranlowo legbe oun, loun
se maa n seto olodoodun naa.
O ni orileede agbaye ko ba ti dun bayii lo ka ni awon asaaju
seto iranwo fawon eeyan gege bi won se maa n se funra won.
Bakan naa ni alaga fegbe oselu APC nipinle naa, Alaaji Tunde
Balogun, ro awon asaaju lati ki alafia se pataki ninu igbe aye won.
O wa gboriyin fun Salvador fun bo se ko mosalasi tuntun naa
fawon eeyan lati maa josin. O ni oun to se yii, ko jo oun loju, nitori bi baba
to bi naa se ko mosalasi nla naa niyii tawon eeyan si n josin nibe di akoko
yii.
Ninu waasi Alaaji Aminulahi Serik, to je Seriki Imaamu fun ekun
Ansar-ud-een Society, Fadeyi, niluu Eko, o ro awon musulumi lati lo akoko awe
ti won wa lati sun mo Olorun, ki won si pofin e mo.
O ni nnkan to n reti latodo awon musulumi ododo lakooko yii ni
iwa omoluabi, mki won si ko ese won sile, ki won ma pada sinu e mo.
No comments:
Post a Comment