Onarebu Moshood Adegoke
Salbador, to ti figba kan je alaga fegbe oselu PDP, ko to darapo mo APC, ti
foko oro ranse si El- Rufai, gomina ipinle Kaduna pe ko koju mose e, ati pe oun
ko ro pe ise to gba ka a lara.
O soro yii lakooko to n ba awon oniroyin soro lojo Aiku, Sannde,
ana, nibi ayeye olodoodun to maa n se fawon musulumi ni akoko awe, nibi to ti
maa n febun tore, eyi to waye nile e, niluu Eko.
O soro yii lati fesi si oro ti Gomina El- Rufai so lori baba-
isale ni nnkan bii ojo meloo kan seyin. O fi aidunnu e han lori oro naa, o si
ni ki i senu okunrin omo Hausa naa lo ti ye kiru e maa jade
Salvador tun salaye pe bi El-Rufai se foro n tebelu Asiwaju Bola
Ahmed Tinubu, tawon gba gege bi olori egbe oselu APC nile Yoruba buru jai, ebun
pataki lo so pe okunrin naa je lagbaye ki i se ni o le Yoruba nikan.
O ni ipa pataki ni Tinubu ti ko ninu idagbasoke ipinle Eko ati
fawon to n gbe ni agbegbe e, o wa ni ki i se iru e ni enikan ti ipinle e ko ni
alafia, to je pe ojoojumo ni won ko awon eeyan e sinu wahala yoo wa maa soro
kobakugbe lee lori.
Eni to tun je alakoso olupolongo ibo aare fun Buhari nipinle Eko,
wa sapejuwe oro Gomina ipinle Kadunaa gege bi eyi ti ko nitumo, kawon eeyan ma
se kaa kun, nitori oun gan-an funra e oro ipinle e ko ye e.
Salvador toka si pe opo awon nnkan lo ye ki El-Rufai sise le
lori nipinle e ti ko se, to je pe kaka bee oro baba isale lo n wa da si nipinle
Eko. O ni awon tawon wa nipinle Eko, awon mo pe awon ko ni isoro pelu asiwaju
won bawo wa ni ti gboro mi deleru, o ni ko ya koju ise e daadaa.
No comments:
Post a Comment