Ki i se
tuntun mo pe ojo kokandinlogbon, osu yii, ni ayeye igbejoba tuntun yoo waye fun
gomina tuntun ti won sese yan nipinle Ogun, Omooba Dapo Abiodun, niluu
Abeokuta.
Ara oto ni ayeye
odun yii, nitori onibeji ni, idi abajo ni pe ojo naa tun ni Gomina tuntun naa
yoo pe odun mokandinlogota to dele aye.
Fun ayeye
onibeji naa, gbogbo eto lo ti wa nile ti igbimo ti won gbe kale lati samojuto
ayeye naa la kale, eyi ti igbakeji gomina tuntun Arabinrin Noimot Salako
Oyedele je olori fun.
Lara awon
eto ti won ti la sile gege bi igbimo olupolongo eto iroyin fun ayeye naa ti
Arabinrin Modele
Sarafa Yusuf- je alaga won se gbe jade se gbe jade ni ayeye ibura ti yoo waye lojo kokandinlogbon,
osu yii, ti yoo waye ni papa isere Moshood Abiola, niluu Abeokuta, Adajo agba
Mosunmola Arinola Dipeolu ni yoo sebura naa.
Bakan naa la
gbo pe ojo ketalelogbon, osu yii, ni awon ayeye naa yoo bere nigba ti
idanilekoo yoo waye ni gbongan Cultural Center, Abeokuta. Ogbeni Fola Adeola to
je oga agba ati oludasile banki GTB ni yoo je alaga lojo naa nigba ti Ojogbon Pat Utomi yoo dawon
eeyan lekoo.
Lojo Eti, Furaide, ti i
se ojo kerinlelogun, ni akanse irun yoo waye
ni mosalasi jimo, Ijebu Odem nigba ti asale asa yoo waye lojo Abameta,
Satide, ni June 12 Cultural Centre, bee ni akanse isin yoo tun waye lojo Aiku, Sannde, ni Anglican
Church Cathedral, Ilaro.
Lojo Isegun, Tusidee,
ojo kejidinlogbon, ni ayeye fifa ijoba le ijoba tuntun yoo waye, nigba ti
gomina to fee kogba sile, Seneto Ibukunle Amosun yoo fa ise le ijoba tuntun
lowo, ti yoo waye ni ofiisi gomina ,Oke Mosan, Abeokuta ,aago mokanla ni eto
naa yoo bere.
Leyin ibura ti yoo
waye lojoruu, Weside bee ni ayeye iweje-wemu ti yoo waye ni ale ojo naa ni ni
gbongan OOPL Events Centre, Abeokuta.
Ojo Eti, Furaide, ojo
kokanlelogbon, ni ayeye naa yoo bere si ni kogba sile nigba ti akanse irun kiki
yoo waye ni mosalasi jimo, Egba Central Mosque, Kobiti, Abeokuta bee tun ni iru
akanse isin ope bee yoo tun waye lojo Aiku, Sannde, ojo keji, osu kefa ni soosi
Cathedral Church of St Peter, Ake, niluu Abeokuta.
I
No comments:
Post a Comment