Leyin wakati mejidinlaadota, Jide Ojuko, komisanna Amosun pada senu ise e. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 17 May 2019

Leyin wakati mejidinlaadota, Jide Ojuko, komisanna Amosun pada senu ise e.



Komisanna foro ijoba ibile ati oye jije nipinle Ogun, Oloye Jide Ojuko ti so pe oun ti pada senu ise oun leyin wakati mejidinlaadota to ti koko kowe fipo sile.

Gege bo se wi lakooko to n ba awon oniroyin soro lofiisi e, o loun gbe igbese naa leyin ti Gomina Ibikunle Amosun ko lati gba iwe ifipo sile naa tawon si ti yanju awuyewuye to mu ipinnu naa wa tele.

Ninu oro e  ni komisanna naa ti so pe oun pe ipade oniroyin naa lati le je ki won mo idagbasoke to tun ti sele leyin toun fiwe sile, o ni leta naa je leta ife laarin awon ololufe meji.

Ojuko ni oun feran Gomina oun bee naa loun naa feran oun pelu. O ni ‘Gomina Amosun ko gba leta ti mo ko, eyi ti mo fi sowo seyin oniroyin, nitori idi eyi, mo ti pada senu ise mi, mo si fee ke e mo pe a ti n sise lori nnkan to mu mi kowe fipo sile tele’

O tun lo akoko naa lati so pe bi won se n so nipa nnkan to wa ninu leta naa yato gedegbe soun toun koo le lori. O wa dupe lowo gbogbo awon eeyan e to n soju lati Ota fun agboye to wa laarin won.

Ojuko ni oun ti jokoo pada sori aga oun gege bii komisanna foro ijoba ibile ati oye jije nipinle Ogun. A o ranti pe lojoruu, Wesidee, ijeta ni iroyin gba igbo
.


No comments:

Post a Comment

Pages