Dapo Abiodun loun yoo sin awon eeyan oun lona tooto ninu ijoba oun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 23 May 2019

Dapo Abiodun loun yoo sin awon eeyan oun lona tooto ninu ijoba oun.




 Gomina tuntun ti won yoo sebura fun lojo kokandinlogbon, osu yii, Omooba Dapo Abiodun, ti muu da awon eeyan ipinle Ogun loju pe ijoba oun yoo sagbara lati rii pe oun se e lona tooto ateyin to ye lati fi sin won, pelu ibowo fun ofin loju ese toun ti won ba ti bura foun.

Bee  lo tun seleri lati fara e kale fun erongba awon araalu lati je ki idagbasoke ba awon ise akanse to nitumo yato sawon eyi ti ko le se awon eeyan ipinle Ogun lanfaani.

Dapo Abiodun soro yii lakooko to n ba awon eeyan soro nibi eto idanilekoo to waye fun ti igbaradi ijoba tuntun, eyi to waye ni gbongan June 12, Culture Center, niluu Abeokuta.

Nibi idanilekoo naa ti won pe akole e ni Isakoso isejoba tuntun lawujo, Gomina ti won sese dibo yan tun salaye  pe loooto ni ipenija yoo wa sugbon ijoba oun yoo rii pe awon sise lori gbogbo awon nnkan ti won ba soro le lori nibi idanilekoo naa, atawon eyi tawon igbimo ti won gbe kale lori isejoba tuntun sise le lori pelu.

Ko to to akoko yii  ni Ojogbon Pat Utomi, to je oludanilekoo, nibi eto naa ti gba Dapo Abiodun nimoran lati rii pe ilaniloye n waye loorekoore laarin awon osise ijoba lona ti yoo je ki erongba e di mimuse nipinle Ogun.

O sakiyesi pe awon ipenija opolo ilera to n koju wa lorileede Naijiria ni lati tete wa opin si iponju to n ba wa finra, o war o gomina tuntun naa lati tete wa ona ti  opin yoo fib a iponju loju ese to ba ti bere ise e.

O sa sapejuwe ona iyanu tawon bii Obafemi Awolowo, Nnamdi Azikwe ati Sardauna gba nigba ti won ti won fi saseyori, o ni iru ore-ofe bee si wa ti gomina ti won sese yan naa ba le loo lawon ona bii eto-eko, aabo,ati ilera pelu awon owo iranwo to ba n towo ijoba apapo wa.

Ninu oro alaga nibi ayeye naa, Tola Adeola, to je oga agba ati oludasile ileese GTB, o ro gomina ti won sese yan naa lati gba ise naa gege bi ise iranse lona to je pe ko ni ya ara e soto pelu awon eeyan igberiko, atawon osise ijoba.

O tun gba Dapo Abodun nimoran lati ma se fi sowedowo to ba je ti ipinle Ogun sapo ara e.


No comments:

Post a Comment

Pages