Igbega Idokowo Ogun yoo tun je koro aje ipinle naa tun lo soke si -Subair - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 24 May 2019

Igbega Idokowo Ogun yoo tun je koro aje ipinle naa tun lo soke si -SubairArabinrin Babi Subair, to je oludamoran pataki fun Gomina Ibikunle Amosun ti muu da awon omo ipinle Ogun loju pe igbega idokowo Ogun atawon eka e yoo tun je ki oro aje ati ipawo-wole sipinle naa tun goke sii.

Obinrin naa soro yii lakooko ti won se ifilole eto naa, eyi to waye Lojobo, Tosidee, ana- an ni gbongan Mitros, Ibara Housing GRA, Abeokuta nipinle Ogun.

O so pe igbega idokowo ti won sese fi lole naa yoo mu ki idagbasoke de ba oro aje kaakiri ipinle Ogun, to fi mo awon igberiko to wa labe e, ti yoo si tun pese ise fawon eeyan lati janfaani labe eto naa.

Subair tun salaye pe won ti fun won ni gbedeke ojo lati rii pe won mu idagbasoke ba idokwo  lona ti yoo tun je ki ajosepo to danmoran wa laarin won atawon to ba fee sese dokowo pelu won pelu atileyin nla lawon ileese nla-nla.

O ni idaniloju wa pe ajosepo oloresore yoo maa waye lawujo, eyi ti yoo fawon olokoowo nile ati oke-okun mora. Bee lo ni eto si n lo lowo lati ri pe won tan imole ileese naa kaakiri awon ileeese, eka ati asoju, bakan naa lawon tun gbe igbese lati ran awon alakoso olokowo kokan lowo nipinle ogun lona isejoba tuntun.

Ninu oro Gomina Ibikunle Amosun, eni ti akowe ijoba nipinle Ogun, Agbejoro Taiwo Adeoluwa soju fun un lo ti so pe laarin odun mejo ijoba to fee kogba wole yii ni won ti sa agbara won lori idasesile, eyi ti ko se fowo seyin lagbaye.

O so pe ileese nla to fee to eedegbeta ni won ti da sile nipinle Ogun atawon ileese kekeke mii in to fee to egberun, eyi to so pe ko ri bee lawon ipinle mii in.

O wa gboriyin fawon to sagbekale ifilole igbega idokowo Ogun naa fawon ipa ti won ti ko lati le je ki oro aje ati ipawo-wole tun lo soke ju bo se wa lo.


No comments:

Post a Comment

Pages