Gbogbo awon to gbo
nipa nnkan to n loo nigboro laarin egbe osere tiata TAMPAN ati ANTP, ni won so
pe oro buruku gbaa ni ati pe kin ni awon egbe osere TAMPAN n fi ara won pe.
Gege bi a se gbo, won
lawon agba osere atawon oloye egbe osere TAMPAN lawon ti dariji Baba Wande ati
Oloye Lere Paimo topo mo si Eda onile ola lati maa lo won ninu fiimu ti won ba
n se.
Logba LTV niluu Eko
loro naa ti taa si wa leti nigba tawon omo egbe naa soro laaarin ara won, koda
won so debi pe laipe yii ni Baba Wande sese kopa ninu fiimu tomo egbe osere
TAMPAN se.
Bee o ba gbagbe ni
nnkan bii odun meloo seyin ni Dele Odule to je aare egbe osere TAMPAN tele pase
pe won ko gbodo pe omo egbe osere ANTP kankan sinu ise tawon omo egbe e ba n
se.
Idi niyii ti won fi pa
awon agba osere naa ti, to je pe won so di ogun laaarin ara won, koda nibi ti
won baa de,aimoye awon ore ni won di ota nitori igbese ti won gbe naa.
Bo tile je nigba to ku
die ki saa Dele Odule pari ni iyato ti n de ba egbe mejeeji ti won si ti n bara
won se, bi bara won se naa, ko debi ise ti won se.
Sugbon nnkan to ya
awon to gbo nipa igbese naa lenu ni pe o se je pe Baba Wande ati Lere Paimo
nikan ni agba ti won so pe awon dariji lati maa bawon sise papo. Iru ese wo ni
won se won tele, ti won fi n febi pa awon baba naa.
Iwadii tun fi ye wa pe
awon agba osere ti won tie wa pelu won ti won jo n sise po, o di fiimu meloo ti
won pe awon agba naa si ati pe nje won tie ranti won.
Nje ohun to dara ni
kawon TAMPAN maa so pe awon dariji awon to gbe kanga ise naa fun won. Okan lara
awon agba osere tiata to wa ni Eko so foniroyin wa pe iran ni oro won sugbon o
dawon loju pe asesile ni abowaba, gbogbo nnkan ti won ba se fawon agba osere
lawon naa yoo gba.
No comments:
Post a Comment