Sunday
Oginni, to je akowe igun kan ninu egbe oselu Labour nipinle Ogun ti so pe
gbogbo ara lawon fi mo igbimo tuntun ti won sese yan lati maa gbo ejo lori
ehonu fun ti ibo gomina to waye ninu osu keta.
Ninu
atejade kan ti okunrin naa fowo si to te wa lowo ni won ti nigbagbo gidi ninu
igbimo ti Onidajo Zainab Bulkachuwa yan
lati wa maa gbo ejo naa.
Onidajo Josephine Coker lo saaju igbimoi to n gbejo awon ni won
yoo si ropo Onidajo Chinwe Onyeabor ti won ti koko yan wa tele sugbon ti won tu
igbimo won kan lori esun kan ti won fi kan won,
Oginni salaye pe awon setan lati sise po pelu igbimo kigbimo ti
won ba gbe wa pelu okan igbagbo.
O ni egbe oselu Labour pelu ejo ti won pe ti nomba e je
EPT/OG/GOV/02/2019 fi atileyin won si igbimo naa laise iye meji.
Won lawon tun nigbagbo pe igbimo naa ko ni sojusaaju lakooko ti igbejo ba n lo
lowo, won yoo si se gbogbo nnkan lona to ba ofin mu.
No comments:
Post a Comment