Opin aye de; Awon omoleewe girama se igbeyawo alarinrin logba ileewe won - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 7 May 2019

Opin aye de; Awon omoleewe girama se igbeyawo alarinrin logba ileewe won
Titi di akoko ti a n ko iroyin yii, iyalenu lo si n je fawon eeyan to gbo nipa isele kan to waye logba ileewe girama kan niluu Bauchi, iyen ileewe Sa’adu Zungur Model, Bauchi, nibi ti won lawon omoleewe girama agba ti se igbeyawo alarinrin laaarin won.

Bo tile je pe a gbo pe ijoba ipinle naa ti pase pe ki won ti ileewe naa pa titi ti won yoo fi pari iwadii won sibe kayefi loro naa si n je.

Gege bi a se gbo, won ni ko sese maa waye laarin won pelu pe otooto ni yara ikawe okunrin ati obinrin, won ni won ti n se tipe ko to di pe asiri oro naa tu sita gbangba.

Won ni okan lara awon oluko ileewe naa ni asiri tu si lowo nigba tawon akekoo ti won wa ni yara ikekoo keji ti agba iyen SS2 dana ariya repete laaarin ara won fun ayeye igbeyawo.

Ariwo ti won n pa lati fi sajoyo lo mu ki tisa naa sare de be lati mo nnkan to n sele, sugbon se lenu yaa nigba to ri pe igbeyawo lokunrin ati  obinrin ti won je omoleewe n se laaarin ara won.

Won ni se ni omoleewe okunrin san eedegbeta naira gege bi owo idana feni to fee fe toun naa je omoleewe ileewe naa.
 Bee ni won so pe awon to je ore oko iyawo naa tun dawo laaarin ara won ti won fi ra ipapanu ti won je lakooko igbeyawo ohun.

Loju ese ti tisa naa ti ri nnkan to n sele lo ti sare ke gbajare loo sodo Mallam Ahmed Zailani,to je oga agba nileewe naa, toun naa si lo so nnkan toju e ri fawon oga tie naa to wa ni ileeese to n ri si oro eko.

Idi niyi ti won ni igbakeji gomina nipinle naa, to tun je komisanna foro eko, Nuhu Gidado se pase pe ki won tileewe naa, eyi to si ti sakoba fawon omoleewe alakobere to wa nibe.

Gege bi atejade ti Yakubu Adamu, to je oluranlowo nipa eto iroyin nipinle naa se wi, o ni inu igbakeji gomina naa ko dun si igbeyawo ti ko bofin mu tawon omoleewe  girama naa se, o ni idi niyi ti won fi tileewe naa pa lati se iwadii. Ati pe gbogbo awon toro naa ba si mo lori ni won yoo fi won jofin.No comments:

Post a Comment

Pages