Atimole awon olopaa ni
Eleweran, ni niluu Abeokuta, ni Arakunrin kan, eni odun mokanlelogbon, Jolly
Gilbert wa bayii lori esun pe ayederu soja ni.
Lojo karun un, osu
yii, lowo awon olopaa to wa ni Ogijo te okunrin ayederu yii lakooko tawon
olopaa n wa awon afurasi jade, ile igbafe kan to wa ni Eyin ogbe, Ogijo, lowo
ti te pelu awon afurasi meji mii in.
Aso awon soja ni won so pe o wa lara e, bi won
si se muu lawon olopaa forowalenuwo, to si so fun won pe omo ogun ti eka 174
Battalion loun.
Idi niyi tawon olopaa
fi te ateranse lati fi mo boya ooto ni sugbon tawon yen so pe iro lo n pa, awon
ko mo on ri, ti won si ni ayederu ni.
Lara awon nnkan ti won
ri gba lowo e ni kaadi idanimo awon soja, obe elenu sonso, aso soja atawon ogun
dudu.
Ni bayii, Komisanna
awon olopaa nipinle naa, Bashir Makama ti pase pe ki won bere iwadii kiakia
lori afurasi naa, ki won si tete gbe e lo sileejo lati foju winna ofin.
No comments:
Post a Comment