Boroboro ni Oni
Olohunwa, eni odun mejidinlogbon n ka ni ogba awon olopaa ni Eleweran, niluu
Abeokuta, lori bo se gun ore e, Baraka Taiwo, lobe pa.
Gege bi Abimbola
Oyeyemi, to je agbenuso fawon olopaa nipinle Ogun, se wi ninu atejade kan to fi
sita, O so pe lojo karun un, osu yii, ni okunrin kan toruko e n je Wasiu Raheem
wa si tesan awon olopaa to wa ni Ogijo.
Nibe lo ti salaye pe
nibi ariya kan ni won wa ti Baraka ti mu oti yo, to si n se kantankantan lati
da ariya naa ru, won ni nibe ni Oni ti loo baa to si so fun un pe ko se suuru,
sugbon ti won ni Baraka gba si odi, tawon mejeeji si so dija.
Ija ni won so pe awon mejeeji naa n ja ti Oni fi loo mu obe
to si gun Baraka ni aya ati eyin, to si subu lule, gbogbo agbara ni won so pe
awon to wa nibe sa, ti won si sare gbe e loo si osibitu amo epa ko boro mo,
nibi ti won ti n toju e lo ti dake.
Loju ese ni Baba
Muhammed to je oga awon olopaa, DPO ni ekun naa ti ran awon omoose e lo sibi
isele naa ti won si mu Oni loo si tesan won.
A gbo pe won ti gbe
oku Baraka loo si mosuari OOU to wa ni
Sagamu nigba ti komisanna awon olopaa nipinle Ogun, Bashir Makama, ti pase pe ki won maa gbe afurasi naa maa bo ni
Eleweran, nibi to wa bayii, to ti n ka boroboro.
No comments:
Post a Comment