Irawo osere
to sese dide bo nidii ise tiata, Toheebat Abiodun Ayeni ti so pelu idaniloju pe
o da oun loju pe oun yoo di olokiki nidii ise tiata toun se,
nitori ise to wu oun lati okan ni.
O soro yii
lakooko to n ba oniroyin wa soro, o so pe lati kekere naa nise naa ti wu oun
lati okan wa, toun si maa n so pe lojo kan loun yoo darapo mo sugbon ti Olorun
ti gbo adura oun bayii.
O salaye pe
bo tile je pe oun naa ti bawon kopa ninu fiimu merin iyen Ekun ola, Aje, Adabi
ati Oriki Ife to sese jade, o loun sese mu eye bo lapo ni, nitori oun mo pe
awon fiimu toun yoo si kopa nibe si n bo ati pe oun ko fee je osere nikan, bi
ko se lati tun maa da fiimu se.
Omobinrin
naa to tun je omo agba maketa kan niluu Abeokuta iyen Ajibola Ayeni topo awon
eeyan mo si Ayeni Ventures tun salaye pe
Mercy Aigbe wa lara awon obinrin
onitiata toun fi se awokose nidii ise naa.
Toheebat to
setan nileewe giga yunifasiti Olabisi Onabanjo, ni Ago iwoye nibi to ti kekoo
nipa isakoso okoowo iyen Business Administration ni nnkan to tun je ki iwuri wa foun nidii ise
tiata to yan laayo ni awon obi oun fowo si, ti won si tun satileyin foun
daadaa.
O ni nnkan
to wa lokan oun bayii ni lati mu ise naa ni pataki, lati fi gbogbo ara se,
nitori ise teeyan ba feran, eeyan ki i ya ole nidi e.
O wa dupe
lowo Baba e toun je maketa fun akitiyan e lori oun lati le je ki oun naa di
gbajumo nidii ise naa, nitori o ni opelope baba oun, nitori boun ba fee se, ti
won ba fowo si, ko si nnkan toun fee se, sugbon won ko je ki ebun ti Olorun
foun di asan.
O lo akoko
naa lati fi polongo fiimu kan to sese jade, iyen oriki ife nibi to ti kopa to
joju nibe.
No comments:
Post a Comment