Ogbeni Ubandoma Ularamu to je alakoso RAMP lakooko to n ba awon oniroyin soro |
Ipinle
marun un la gbo pe won ti je anfaani atunse ona igberiko labe ijoba apapo labe
ileese to n si sisatunse awon ona to wa ni igberikoi iyen National Coordinator,
Rural Access Mobility Project (RAMP), ki nnkan ba le rorun fun ise ogbin atawon
agbe ni orileede yii.
Ogbeni
Ubandoma Ularamu to je alakoso ileese naa lo soro yii lojoruu, Wesidee, niluu
Calabar lakooko ti won se idanilekoo eyi ti osise idagbasoke
ibaraenisoro,tileese RAMP sagbateru e.
O so pe
ohun pataki to je ileeese naa loju ni lati maa wa bi atunse yoo se de ba awon
ona igberiko lawon ipinle ti won kopa nibi akanse eto naa. O so pe awon ipinle
marun un ti won ti setan fun eto naa ni.Osun, Imo, Enugu, Adamawa ati Niger .
Bee lo ni
awon ipinle mejidinlogun kan lawon tun ti setan lati sagbeteru won pelu awon
orisirisi ileeese idagbasoke tawon jo n sise po, lara won ni banki agbaye, ajo to n ri si idagbasoke banki
nile Africa iyen African Development Bank (AfDB),atawon mii in.
Declan Okpalaeke, Muyiwa Popoola ati Abigail Ogwezzt-Ndisika, awon oludanilekoo nibi idanileko olojo marun un naa |
Ularamu
tun salaye pe ogota milionu dola lawon ipinle kookan yoo gba lati fi seto
iranwo eedegbeta kilomita atunse awon ona ati sise biriji sawon odo lawon
igberiko naa. Sugbon saa o, ida meta ninu owo naa lawon nireti pe awon ipinle
naa yoo san lati fi lowo si eto naa.
Gege
bo tun se wi, o ni awon nnkan tawon wo fawon ipinle ti won ti dagba soke pelu
ajo banki agbaye, eyi to so pe o nii se pelu isejoba, o ni awon tawon wo naa
nii pelu oselu, eyi to so pe ipinle Cross River janfaani akoko ninu eto naa
nitori oju ojo won dara, ko si si wahala nipinle naa.
Alakoso
ileeese naa ni idi niyii tawon fi mu awon eeyan won wa si ipinle Cross River
lati wa wo awon ise akanse ti won ti se nibe kawon naa si ri eko ko.
Awon olukopa nibi idanilekoo naa |
O wa ro
awon agbasese ti won sise lawon igberiko naa lati gba awon osise lawon agbegbe
ibi ti won ti n sise, eyi yoo si je anfaani lati pese ise fawon ti ko ni, tawon
naa yoo si ni ipin ninu ise naa.
Bee lo
menuba isoro to n dojuko won bii airowo,aini ifowosowopo pelu awon agbegbe ati
abo ti ko peye,sugbon o ni awon sa agbara won lati wa ojutu si ipenija won yii.
O wa ro
gbogbo olukopa nibi idanilekoo naa lati lo anfaani ti won ri yii fi polongo ise
ti RAMP se, ko le saseyori.
Bakan naa
ni Dokita Sam Abah, to je lara awon oluwadii so nibi eto naa pe osi ati iponju
je okan lara isoro to n ba awon eeyan agbegbe igberiko finra lorileede yii, bee
lo ni ko si ipinle ti ko foju winna e pelu.
O wa so pe pelu bi nnkan se n loo yii, igba ti
osise idagbasoke ibaraenisoro yoo ba fi bere ise ni perei, ti won tan imole RAMP
kale awon eeyan ti won jo sise po, won yoo rii pe atunse ba awon igberiko wa
daadaa. O ni owo ti wa nile sugbon bise naa se n lo ni ko tii dara to.
Gbogbo
awon to kopa nibi idanilekoo naa ni won gboriyin fun Oloye Audu Ogbeh to je
minisita feto ogbin lorileede yii lori bi won se sagbekale eto naa, won ni
ogbon tawon ko nibi idanilekoo naa yoo wulo fawon tawon ba de ipinle won.
No comments:
Post a Comment