Oro buruku; Won lawon egbe osere tiata TAMPAN dariji Baba Wande ati Lere Paimo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 7 May 2019

Oro buruku; Won lawon egbe osere tiata TAMPAN dariji Baba Wande ati Lere Paimo


Gbogbo awon to gbo nipa nnkan to n loo nigboro laarin egbe osere tiata TAMPAN ati ANTP, ni won so pe oro buruku gbaa ni ati pe kin ni awon egbe osere TAMPAN n fi ara won pe.

Gege bi a se gbo, won lawon agba osere atawon oloye egbe osere TAMPAN lawon ti dariji Baba Wande ati Oloye Lere Paimo topo mo si Eda onile ola lati maa lo won ninu fiimu ti won ba n se.

Logba LTV niluu Eko loro naa ti taa si wa leti nigba tawon omo egbe naa soro laaarin ara won, koda won so debi pe laipe yii ni Baba Wande sese kopa ninu fiimu tomo egbe osere TAMPAN se.

Bee o ba gbagbe ni nnkan bii odun meloo seyin ni Dele Odule to je aare egbe osere TAMPAN tele pase pe won ko gbodo pe omo egbe osere ANTP kankan sinu ise tawon omo egbe e ba n se.

Idi niyii ti won fi pa awon agba osere naa ti, to je pe won so di ogun laaarin ara won, koda nibi ti won baa de,aimoye awon ore ni won di ota nitori igbese ti won gbe naa.

Bo tile je nigba to ku die ki saa Dele Odule pari ni iyato ti n de ba egbe mejeeji ti won si ti n bara won se, bi bara won se naa, ko debi ise ti won se.

Sugbon nnkan to ya awon to gbo nipa igbese naa lenu ni pe o se je pe Baba Wande ati Lere Paimo nikan ni agba ti won so pe awon dariji lati maa bawon sise papo. Iru ese wo ni won se won tele, ti won fi n febi pa awon baba naa.

Iwadii tun fi ye wa pe awon agba osere ti won tie wa pelu won ti won jo n sise po, o di fiimu meloo ti won pe awon agba naa si ati pe nje won tie ranti won.

Nje ohun to dara ni kawon TAMPAN maa so pe awon dariji awon to gbe kanga ise naa fun won. Okan lara awon agba osere tiata to wa ni Eko so foniroyin wa pe iran ni oro won sugbon o dawon loju pe asesile ni abowaba, gbogbo nnkan ti won ba se fawon agba osere lawon naa yoo gba.

No comments:

Post a Comment

Pages