Lojiji
niroyin gba igboro Abeokuta kaakiri pe Oloye Jide Ojuko, to je komisanna foro
ijoba ibile ati oye jije nipinle Ogun labe akoso Gomina Ibikunle Amosun ti kowe
fipo sile pe oun ko ba oga oun sise po mo.
Iyalenu lo
si n je fawon eeyan nitori ko ju ojo merinla loo mo bayii tijoba taa wa ninu e
yoo kogba sile, idi niyii ti won fi n beere lowo ara won pe kilode ti okunrin
to wa lati Ota naa ko se ni suuru, koun ati oga e jo se ayeye idagbere.
Ninu leta ti
komisanna to kowe fipo sile ko, eyi ti eda e te wa lowo, to ko lojo kerinla osu
yii si Gomina Amosun nipase ofiisi akowe ijoba nipinle Ogun, lo ti koko fi
idunnu e han fun ore ofe ti won fun un ni saa keji ti won gbakoso.
O ni ore-ofe lailai toun ko le gbagbe ni. O wa
ni o dun oun pelu ogbe inu lati fakoko naa so fun oga oun, gomina, toun nifee
gan-an pe oun ko le ba sise po mo.
Ojuko tun
salaye ninu leta e pe ‘Se e mo pe gege bi e se yan mi, mo soju awon eeyan mi
lati Awori, ijoba ibile mi ati ipinle lapaapo, mo setan lati pada sile ni
alaafia sodo awon ebi mi, ki n le ni ifokanbale’.
‘Awon nnkan
to n sele lakooko yii ti je ki n nigbagbo pe nnkan ko le senure ti mo n ba te
siwaju lati maa sise po pelu ijoba to wa lode gege bi komisanna ti mo je. Ati
gege bi ojo ori mi, mi o ni ja mo nnkankan loju awon eeyan mi’.
O ni pari
oro e pe gege bi oye toun ti ni nidii ise ijoba omoose gbodo je olooto si oga e
ni sugbon nitori awon ase e lori oro oloba de ni Ota, eri okan mi n da mi lebi
pe mi o se ise awon eeyan mi. Mi o si gbodo tun maa te siwaju bayii lo.
O wa ni titi di akoko yii, oun si gba Gomina
Amosun gege bi oga,egbon ati asaaju ninu oselu.
Pelu nnkan
to sele yii, o fee je pe oro oloba de
lagbegbe Ota ti
Ojuko ti fee maa gbojubi lodo awon eeyan e, lo se kowe fipo
sile. Nitori ko fee tori Ede ba ode je.
No comments:
Post a Comment