Ayeye odun keje eto How Una dey yoo waye lojo Isegun, Tusidee, ose to n bo - BO SE RI

Breaking

Wednesday 15 May 2019

Ayeye odun keje eto How Una dey yoo waye lojo Isegun, Tusidee, ose to n boGbogbo eto lo ti n lo lowo bayii fun ayeye odun keje ti won ti n seto oloyinbo kan ti won n pe n ni How Una dey lori telifisan OGTV, niluu Abeokuta.

Gege bi atejade kan ti Ogbeni Kehinde Soaga, to je agbeteru eto naa fi sita, lojo Isegun, Tusidee, ose to n bo, tii se ojo kokanlelogun, osu taa wa yii ni ayeye naa yoo waye ni gbongan Providence, to wa ni Abiola Way,lona NNPC, niluu Abeokuta. Bere ni deede aago merin irole.


Eto How Una Dey lo maa n waye ni gbogbo ojo Abameta, Satide, lati aago mesan-an abo si mewaa abo aaro, nibi ti okan-o-jokan awon eeyan lawujo ti kopa ninu e, nibi ti Kehinde Soaga ati Afeez Ayetoro topo mo si simply Saka ti maa n gba awon eeyan lalejo.

Gomina Ibikunle Amosun ni yoo je alejo pataki lojo naa, bee lawon osere naa yoo tun dabira pelu. Mista Latin ati Segun Arinze ni oludari, nigba tileese Kshow multimedia  sagbateru ayeye naa.

No comments:

Post a Comment

Pages