Gomina tuntun nipinle Ogun,
ti won yoo se ibura fun lojo kokandinlogbon, osu yii, Omooba Dapo Abiodun, tun
ti mu da awon osise nipinle Ogun loju pe gbogbo ileri toun se pelu won lakooko
ipolongo oun loun yoo mu se fun won.
O soro yii ninu
atejade kan to fi sita eyi to fi ki awon osise ku ayajo won ti won se loni in,
nibe lo ti sajoyo pelu won.
Atejade naa tun ka
bayii' Mo bawon egbe osise sajoyo ayajo ti won n se loni in, inu mi dun pe
ayeye ti won se lodun yii je nnkan ayo ati ipadabo sijoba ti yoo bere lojo
kokandinlogbon, osu yii”.
“Ki e Ie mo pe mi o
gbagbe mo fee mu wa si iranti yin lara awon ileri ti mo se lakooko ipolongo
lati le mu igbe ayederun fawon osise, ki e le mo pe mo fi yin sokan.
Idasile ileese ti
yoo maa ri bawon osise yoo se maa se daadaa ati imuayederun fun won.
Gbigba awon oluko
sise lona ti yoo dogba pelu awon osise ijoba.
Sise atunse lori
awon osise feyinti ati idasile egbe awon osise feyinti tipinle ati lawon
ijoba ibile atawon nnkan mii in ta jo so papo.
Bakan naa lo tun
fikun oro e pe gbogbo ona lawon yoo tun gba lati rii pe awon samulo ofin to
gbe igbimo laarin awon osise ati asoju awon osise lati sise lori awon
owo ajemonu ti won je awon osise.
O ni ose akoko ti
won ba gbakoso ni won yoo sagbekale igbimo naa.
Dapo Abiodun tun so
pe awon yoo rii pe awon osise nu awon asoju rere ninu ijoba oun eyi ti yoo je
ki irepo tun wa laarin won.
O wa ro awon osise
ki won lo akoko yii lati satileyin fawon tijoba tuntun ba bere nipinle Ogun.
|
No comments:
Post a Comment