Ayeye odun ilu lilu tun mu isokan bawon osere- Kehinde Soaga - BO SE RI

Breaking

Tuesday 30 April 2019

Ayeye odun ilu lilu tun mu isokan bawon osere- Kehinde SoagaOgbeni Kehinde Soaga, to je agbateru fegbe apapo osere omo bibi ipinle Ogun, to tun je omo igbimo awon to n sagbeyewo awon fiimu to n jade nile wa, ti so pe ara aseyori ti ayeye odun ilu lilu to waye lose to koja tun mu wa ni isokan laarin awon osere.

O soro yii lakooko to n ba oniroyin wa soro, O ni pelu bi oun ati Ogbeni Bolaji Amusan, topo mo si Mista Latin se jo sise papo tun mu ki ayeye naa tun larinrin lara oto.

O fikun oro e pe Ijoba gomina to n sese fee kogba sile lojo kokandinlogbon, osu karun un, osu yii, Seneto Ibikunle Amosun ri egbe awon osise gege bii olubasise po ninu idagbasoke.
 Gbogbo igba ti won ba ni nnkan akanse ise ilu ti won ba fee se lo ni won ki i fawon seyin. O ni gege bi osere tawon je si duro gboingboin, igbakigba ni won maa n kan sawon.

Soaga wa fi bi ariwo nla se so lakooko toun ati Odunlade Adekola  yo sibi asekagba ayeye odun ilu lilu naa, eyi to tumo si pe ipa tawon osere n ko ko kere lawujo.

 Fun odidi ojo meta ti won fi se ayeye odun ilu lilu lawon osere ko fi gbeyin.No comments:

Post a Comment

Pages