Gbogbo eyin ti Gomina
to fee kogba sile ninu osu yii, nipinle Ogun, Seneto Ibikunle Amosun, ba fun
nise tabi igbega, ateyin ti won fun ni ade gege bi olori ilu, tee ti n gbalu, tee
n jo, eti yin meloo? akoko ayo yin ko tii to, nitori o se e se ki nnkan tee ro
sele.
Idi abajo ni pe ijoba
tuntun ti yoo gbase lojo kokandinlogbon, osu yii, eyi ti Omooba Dapo Abiodun
yoo di gomina ti so pe gbogbo awon eeyan won yii nijoba e yoo sagbeyawo lori
ade ori, ise ati igbega ti won gba loju ese ti won ti won ba sebura fun un.
Ninu atejade kan ti
Ogbeni Tunde Oladunjoye, to je akowe olupolongo fegbe oselu APC fi sita, lo ti
so pe gbogbo awon toro naa kan lo se e se ki nnkan ayo wonyii ma tun te won
lowo.
Okunrin naa so pe lati
ojo kesan an, osu keta, ti won ti dibo yan gomina tuntun lawon ti pakiyesi awon
onileese okowo ati banki lati ma se ba ijoba to n loo yii lowo dowo po nitori
bigba ti won ba fowo won se saara ni.
Tunde Oladunjoye tun
so pe loooto ni won ti jo fowosowopo da igbimo ti yoo sagbekale ijoba tuntun
sile laarin awon mejeeji, sugbon o se won laanu pe pelu akoko ranpe to ku ti
Amosun yoo fi gbe ijoba, se lo n fawon eeyan ni ise akanse, bee lo tun gbawon
osise sise lai je kijoba tuntun mo nipa e.
O ni iyalenu lo je pe
Amosun gba awon eeyan pupo sise niwonba perete to ku ti yoo gbejoba sile lati
fi le da wahala sile fun ijoba tuntun.
Idi niyi tawon fi tete
kan sawon toro kan lati ma se yo layoju lakooko yii, nitori ese won si mi nile,
idaniloju ko tii wa fun won.
No comments:
Post a Comment