Lojo
Isegun, Tusidee, ni ijoba ipinle Ogun, sagbekale ifilole egbe alaabo ti won pe ni SO SAFE
CORPS, leyin tile igbimo asofin ti fowosi idasile ileese naa.
Ileese
yii ni yoo ropo fijinlante ipinle Ogun iyen VSO ti won n je tele tawon naa si
ti dominira labe ipinle Ogun.
Nibi
ifilole naa to waye ni ofiisi akowe ijoba ipinle Ogun, ni
Agbejoro Taiwo
Adelanwa, to je akowe ijoba ti salaye ipa ribiribi tawon alaabo naa ko nigba ti
won si n je fijilante ko to di pe won yi oruko pada bayii.
O
ni won wa lara awon to je ki eto abo ipinle naa gun rege sii yato sodun 2011 ti
won sese gbajoba, bee lo ni opo aseyori lawon eeyan naa ti se pelu, eyi to mu
ki ipinle Ogun gba awoodu lorisirisi lorileede yii ati oke okun nipa eto abo.
Adeoluwa
tun fikun oro e pe ijoba ipinle Ogun mo riri ise awon eeyan naa, o ni ki won
tera mo daadaa ki won ma si se
kaare rara.
O
wa so pelu idaniloju pe pelu bi won se se agbekale ifilole ileese naa leyin
tile igbimo asofin tipinle Ogun ti fowo si, ko sijoba kankan to le da won duro
niwogba ti won ti so di abadofin.
Ninu
oro Soji Gazzalo to je oga agba fun ileeese alaabo naa, o dupe lowo ijoba
ipinle Ogun bi won se sagbekale SO- SAFE CORPS.
O
menuba awon aseyori ti won ti se lateyin wa bee lo mu da gbogbo omo ipinle Ogun
loju pe gbogbo igba lawon yoo maa pese abo fawon eeyan ati pe titi di akoko yii
lawon si n fawon osise won ni idanilekoo loorekoore.
No comments:
Post a Comment