Egbe oselu All
Progressives Congress, (APC), nipinle Ogun ti ke si Gomina Ibikunle Amosun, pe
dandan ni lati san ele lori owo ti won je awon osise, lori bi won se n san awon
owo ti won yo, atawon asansile owo ti won je won tele bayii.
Oro yii jade ninu
atejade kan ti Ogbeni Tunde Oladunjoye, to je akowe fidihe olupolongo fegbe
oselu naa fi sita losan-an oni, lo ti salaye pe ko si nnkan to se pataki ninu nnkan Amosun se
fawon osise to je babara, to ba je pe loooto lo n san ajesile owo to n san naa.
Oro naa tun lo bayii ’O
ye ki oju gba Amosun ti, nitori ko si nnkan babara to se lati fi gbe awon osise
rara. O ye ko san ele pupo lori owo to fee san fawon osise nitori sebi o ko owo
naa si banki nibi ti ele ti n gun ori e, aimoye bilionu lo ti gun awon owo naa’.
O ni o ye ko san owo ele lori owo awon osise
naa nitori opo awon banki to
kowo naa pamo si lo ti niye ti won ri lori e lodun.
O wa beere lowo Amosun
pe nibo lo ti wa n ri owo to na nigba ti ko si owo ti won n lori epo, ti ko si owo
idapada Paris club, ti ko si tun si owo iranwo latodo ijoba apapo.
Oladunjoye
tun salaye pe “Ka ni Amosun san
owo awon osise naa lakooko to ye, eyi to
fi sowo, opo emi to ti sofo ni ko ba si
wa laye titi di oni.Bee ni opo ebi ni yoo ti mo nnkan ti won fi se ju bo se fi
ko elomii in sinu eje ruru ati orisii aisan mii in.
O wa ran Gomina Amosun
leti lati san gbogbo owo osu ti won je awon osise ileewe giga ati owo awon
tijoba ibile ti won n yo.
No comments:
Post a Comment