Ijoba ipinle Ogun ti gbe opa ase le Oba Abayomi Banjo, gege bi Olokine ti Ojowo tuntun, ni Ijebu Igbo, nijoba ibile idagbasoke Ijebu Igbo West.
Nibi ayeye ifinijoye naa ti won se ni logba
ileewe Ijebu Igbo Girls Grammar School, Ojowo, Ijebu Igbo. Ninu Gomina Ibikunle
Amosun, tipinle Ogun, eni ti Ogbeni Adesoji Adewuyi , to je alakoso nipa oye
jije nileese naa je loruko e lo ti ro oba tuntun naa lati sin awon eeyan fun
ipese oun idagbasoke niluu naa atawon agbegbe e.
O ni igbagbo oun
ni pe Oba naa yoo fowosowopo pelu awon oba alaye yooku ni Ijebu lati kopa
pataki fun igbega asa atawon nnkan mii in fawon eeyan e ati ipinle Ogun lapapo.
Bee ni Gomina Amosun tun dupe lowo awon eeyan ilu naa paapaa
julo awon igbimo olobade fun ifowosowopo won lati nnkan bi odun mejo seyin to
ti n sakoso ipinle naa fawon aseyori to ti se lawon akoko naa.
Ninu oro Oba Banjo, o dupe lowo ijoba ipinle ogun ati
igbimo olobade ni Ijebu ati gbogbo awon to lowo si oye oba to je naa, o wa
seleri pe lakooko oun, oun yoo sa ipa lati ri pe gbogbo omo ilu naa lo jafaani
ninu ijoba oun laise ojusaaju.
Ko to to akoko yii ni
Onarebu Adegoke Adekanbi to je alaga idagbasoke ijoba ibile Ijebu Igbo
West ti dupe lowo ijoba ipinle Ogun lori
ifinijoye oba tuntun naa.
No comments:
Post a Comment