Bo tile je
pe aago mokanla aaro, ojo Isegun, Tusidee, ni won pe ayeye gbigbe ijob a
tuntun le gomina tuntun ti won sese yan,
Omooba Dapo Abiodun lowo sugbon eto naa ko bere titi di aago meta koja osan ojo
naa.
Idi abajo
lawon eto kan ti Gomina to kogba sile, Seneto Ibikunle Amosun se latile yanju
gbogbo ise to wa lowo e. Bo si ti setan, tawon olopaa sayeye idagbere fun un,
ti won si fi moto isayeye ikeyin gbe de enu ona abawole ofiisi gomina ni ayeye
igbejoba kale naa waye.
Akowe ijoba
ipinle Ogun, to sese kogba sile naa, Taiwo Adeoluwa lo soju Seneto Ibikunle
Amosun nigba ti igbakeji gomina tuntun, Noimot Salako Oyedele, soju Dapo Abiodun nibi eto naa.
Pelu
ayo ati idunnu ni Adeoluwa fi gbe akoso ijoba tuntun le igbakeji gomina lowo,
Ninu ise ti igbakeji
gomina tuntun naa je loruko oga e,Dapo
Abiodun, o ki Seneto Ibikunle Amosun ku oriire aseyori to se fun odidi odun
mejo to fi sakoso ipinle naa.
O so pe opo ise nijoba
to kogba sile naa lati bi odun mejo seyin ati pe gbogbo wa la mo pe ijoba n
tesiwaju ni, o wa seleri pe Dapo Abiodun yoo tesiwaju nibi ti ijoba to kogba
sile naa ba de lati le je ki gbogbo eeyan je mundunmundun ijoba e.
Bee lo tun dupe lowo
gbogbo awon eeyan bi won se tu jade lati wa sibi eto igbajoba kale fun ijoba
tuntun naa. O ni bi ose meloo kan lawon se ipade po lori igbejoba kale, ti o sib
o si rere.
Ninu
oro ti Taiwo Adeoluwa, to je akowe ijoba to kogba sile, o dupe lowo Olorun fun
atileyin e to se lati je kawon saseyori fodun mejo ti won ti n se ijoba.
O
wa ro ijoba tuntun lati je ki oro awon eeyan je koko lokan won, ki won si
tesiwaju nibi ise rere ti Amosun to fee kogba sile naa fi sile.
No comments:
Post a Comment