Lati le fi
emi imoore han, awon osere lapapo lorileede yii fun Gomina tele nipinle Ogun,
Seneto Ibikunle Amosun ni awoodu fawon nnkan to ti se fun won laarin odun mejo
to fi se ijoba.
Nibi ayeye
idagbere ti won se fun gomina tele naa, to waye ni gbongan Amphi- Theatre, to
wa ni Oke- Ilewo lawon osere naa ti fun lami eye naa.
Gege bi
Afeez Oyetoro topo mo si simply Saka, se wi lakooko ti won fee fun Amosun ni
awoodu naa,o lawon mo ipa ribiribi ti okunrin naa ti ko fawon osere, eyi ti ko
se fowo ro seyin.
O ni Amosun
je gomina to feran awon osere lakooko to wa nipo naa ati pe ore awon lo je, idi
niyi tawon naa fi forikori lati fun okunrin naa ni ami eye pe awon dupe oore e
lori won.
Ninu oro ti
Gomina tele naa, o dupe lowo awon osere fun awoodu ti won foun yii, o wa so pe
loooto loun ti fipo gomina sile, sugbon ajosepo to wa laarin won ko le kuro.
Oun naa wa
dupe lowo awon osere yii fun atileyin won ni gbogbo igba toun se akoso
ipinle Ogun, nitori oun naa mo ipa won
laarin ilu.
Lara awon
osere to wa nibe ni Segun Arinze, Racheal Oniga, Adewale Eleso, Richardco, Bimbo Akinsanya, Toyosi Adesanya, Dejo Tunfulu,
Afees Oyetoro, Kehinde Soaga to se agbeteru awon osere naa atawon osere mii in.
No comments:
Post a Comment