Dapo Abiodun gomina tuntun ti won bura fun loun ko nii dale awon eeyan oun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 29 May 2019

Dapo Abiodun gomina tuntun ti won bura fun loun ko nii dale awon eeyan oun
Omooba Dapo Abiodun,gomina tuntun n ipinle Ogun, ti muu da gbogbo awon eeyan ipinle loju pe ijoba oun ki i se ti molebi rara pelu ileri pe oun ko ni dale awon eeyan naa.
Gomina soro yii lakooko ti won se ibura foun ati igbakeji e, Arabinrin to tun je onimo-ero Salako/Oyedele, yet to waye ni papa isere ni MKO Abiola, to wa ni Kuto, niluu Abeokua.
Adajo Mosunmola Dipeolu, to je adajo agba nipinle Ogun lo se ibura fawon mejeeji fun ti gomina ti won dibo yan eleekarun ijoba tiwa-n-tiwa.
Nibe ni Gomina ti so fawon araalu pe oun ko nii dale awon eeyan ti won nigbagbo ninu oun, ti won dibo yan oun wole. O ni oun yoo sejoba naa gege bi Omoluabi ati pea won yoo jo maa pinnu papo lati sejoba.
Bee lo so pe ijoba oun yoo se atunse tooto lori  osise araalu,awujo awon ijoba ibile ati atunto lori idanilekoo,idasile ina igbalode lawon igberiko wa. ects in the rural areas.
Gomina Abiodun tun so fawon aye yoo si sile fawon odo atawon mii in ti ko nise lowo. O ni iroyin ayo toun ni fawon eeyan ipinle Ogun lojo naa ni pe oun yoo saaju ijoba oun ninu ooto ati ifokansin, laisi ojusaaju Kankan ninu e.
O wa lo akoko naa lati kilo fawon odaran, ajinigba awon omoota lati ma se fi ijoba oun sere nitori eto abo lo je oun logun julo n inu isakoso oun yii.
Gomina naa tun salaye pe isakoso ijoba oun yoo koju mo isakoso okoowo bee lo seleri pe atunse yoo de ba awon ona to ba je ni igberiko atawon ilu ti won jo laala papo, apero lori eto eko lo so pe won yoo tun gbe dide pada, bee ni ile itoju yoo tun kaakiri igberiko pelu.
No comments:

Post a Comment

Pages