Lojo Aiku,
Sannde, ti se ojo kejila, osu karun un, odun yii, ni egbe akorin, Golden Voice
, ijo Kerubu ati Serafu, Ebenezer Communion, yoo se ajodun won nile ijosin won to wa ni
Oke- Bukun, lona Adesanmi, Asero, niluu Abeokuta . Aago mewaa ni isin yoo bere
lojo naa.
Gege bi atejade
ti Ogbeni Iseoluwa Bankole, fi sita lo ti so pe ojo Abameta. Satide, ojo
kokanla, ni won yoo ti bere eto
alarinrin fun ti ajodun won naa.
Lara eto ti
won ni lojo Abameta naa ni idanilekoo, orin iyin , atawon
nnkan mii in, sugbon ojo keji tii se ojo Aiku, Sannde, ni ajodun yoo waye nibi tawon omo egbe akorin
naa yoo ti fi orin okan-o- jokan da awon eeyan laraya. Olorin juju nni Lekan
Fasola, naa yoo korin lojo naa.
Oniwaasu ojo
naa ni Apostle Wole Adelekan, lati ijo Eagle Christian Mission to wa ni
Iberekodo, Abeokuta, Bakan naa ni won yoo tun fami eye da awon kan lola lojo
naa.
Lara awon ti
won n reti lojo naa ni Oloye Arabinrin Bola Obasanjo, iyawo Oloye Olusegun
Obasanjo, aare tele lorileede yii, oun ni mama ojo naa, nigba ti Alagba A O
Thomas yoo je baba ojo naa.
No comments:
Post a Comment