Wahala kekere ko lo n koju awon igbimo ti
Dapo Abiodun, gomina tuntun yan, ti yoo sagbekale
eto fun gbigba akoso tuntun ipinle Ogun, lojo kokandinlogbon, osu.
Idi abajo ni pe gbogbo awon ibi ti won fee
lo fun eto naa to ye ki won samojuto ni won nijoba to wa lode yii ko je ki won
de be titi kan papa isere ni won ko je ki won de be.
Asiri oro yii tu si wa lowo nipa leta ti won
ko si igbakeji gomina ti won sese dibo yan, Arabinrin onimo-ero Noimot
Salako-Oyedele lati ofiisi akowe ijoba ipinle Ogun, Adeoluwa Taiwo.
A gbo pe igbakeji gomina
naa lo saaju igbimo ti yoo sagbekale ijoba tuntun nigba ti akowe ijoba ipinle
Ogun saaju ijoba to fee ko gba sile naa.
Leta ti akole e je ‘Si sabewo awon ibudo pataki’ ti won ko lojo
kejo, osu yii ni won ti so fun won pe
won ko ni le raye de ibi awon ibudo naa.
Bi leta naa se loo niyii"
Eyi ni lati so fun yin lati da esi leta ti e ko pada, Gomina Ibikunle Amosun, ti pase pe ki a sise po pelu ifowosopo pelu
igbimo yin fun iranlowo fun ti ayeye igbajoba tuntun, sugbon ipenija to kan wa
nibe ni ti awon ibudo tee lo, to wa ninu leta yin awon ibudo bii "Valley
View, Presidential lodge, Mitros Suite, June 12 Cultural Centre, Stadium",
gbogbo e la si n lo lowo bayii, yoo si to igba die si ojo kokandinlogbon, osu
yii ko to le wa nile gege bi a se saaju lakooko taa jo sagbekale igbimo lojo
kokandinlogbon, osu kerin to koja,
Bee ni won tun so ninu leta naa pe gege bi won se mo pe ipinle
Ogun n gbaradi igbalejo aare Muhammadu Buhari, lati wa si awon akanse ise, eyi
ti yoo waye ninu ose keta osu yii, atawon nnkan mi ni won so pe o fa idiwo ti
won ko fee fi gbe awon ibudo naa kale.
Nigba to n fese oro naa mule, Ogbeni Tunde Oladunjoye, to je
akowe olupolongo fegbe oselu APC, nipinle Ogun, o fidi oro naa mule pe loooto
ni ati igbimo ti Gomina Amosun gbe kale ti akowe ipinle saaju fun ko fowosowopo
pelu won rara lati le je ki ayeye ojo naa
lo bo se ye.
No comments:
Post a Comment