Gomina tuntun ti won
sese yan nipinleOgun, Omooba Dapo Abiodun, ti ranse ikini ku oriire ayeye
ojoobi odun ,karundinlaadorun Alayeluwa Oba Sikiru Kayode Adetona, Awujale tile Ijebu, to si tun je olori oba ni
gbogbo ile Ijebu.
Ninu atejade kan ti
Agbenuso fun Dapo Abiodun, Remmy Hazzan fowo si losan-an oni in loruko gomina
tuntun naa, eyi to te wa lowo, lo ti ba gbogbo omo ile Ijebu tile-toko sajoyo
ojoobi Oba Awujale naa.
Ninu oro e lo ti
sapejuwe Awujale ile Ijebu gege bi oba to maa n duro lori oro e, to si fun ara
lowo, iyi ati ola, ti ko si bawon si ninu ki nnkan daru.
Bee lo ni Oba Sikiru
Kayode Adetona maa n sa ipa re gege bi baba lati le je ki isokan wa, bee lo ni
opo igba lo ti saaju lori oro aje ati idagbasoke lori asa nile Ijebu.
O wa gbadura fun Oba
naa pe yoo tubo pe laye, yoo si tun gun lemi ninu ara pipe ati ilera.
No comments:
Post a Comment