Wahala Ifo; Won wa olopaa tawon omo egbe okunkun sa l’adaa - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 22 April 2019

Wahala Ifo; Won wa olopaa tawon omo egbe okunkun sa l’adaa

 - bee lowo ti te afurasi meedogbon


 Afurasi meedogbon lowo awon olopaa ipinle Ogun ti te lori wahala kan to sele nibi ayeye ti won pe ni Akoogun to waye niluu Ifo, nibi ti won ti femi eeyan sofo, topo awon eeyan farapa, ti won si n wa olopaa kan titi di akoko yii.

 Rogbodiyan to waye lojo Aiku, Sannde, la gbo pe awon afurasi omo egbe okunkun ti doju ija ko ara won lori ede aiyede ti won si tun dana sun ofiisi igbakeji olori ile igbimo asofin nipinle Ogun, Olakunle Oluomo, to wa ni boosi toopu Coker
.
Gege bi Agbenuso fawon olopaa nipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi, se wi, Moto nla marun un to je ti Oluomo lo fidi e mule pe won dana sun leyin to ni won jo ofiisi e tan.

O so pe titi di akoko taa n ko iroyin yii lowo lawon si n wa olopaa insipekito kan tawon ko ri latigba tisele naa ti waye. O ni olopaa naa ni won sa ladaa nigba tawon to n ja naa doju ija ko awon olopaa.

Bee  ni Oyeyemi tun so pe ota ibon loo ba Odomokunrin kan ti won pe oruko e ni Akeem to si ku patapata lakooko tija naa be sile.

Nigba to n so bii wahala naa se waye lojo naa, Agbenuso awon olopaa so pe awon olopaa to wa ni Obada nijoba ibile  Ewekoro, ni won mu okunrin kan ti won fura si pe won ri ibon lowo e lona aito nibi ayeye naa sugbon tawon omoota ko je ki won mu, won ni afurasi naa lo daruko elomii in to je omo egbe okunkun ti gbogbo awon wa.

O salaye pe won ti mu onitohun ni Ifo sugbon bi won se n lo lo ni awon toogi naa dena de won lati gba afurasi naa sile, nitori lati raye lo lo mu kawon olopaa yinbon soke,ti ota fi lo ba Akiimu to ku.

O ni ko pe sigba naa ni awon eeyan naa gba ofiisi Oluomo to wa ni Coker  lo ti won si dana sun moto marun un nibe. O wa sapejuwe isele naa gege bi eyi to buru ju, pelu ileri pe gbogbo awon to kopa ni won yoo fi won jofin


No comments:

Post a Comment

Pages