-Lokunrin naa ba n japoro kaakiri
Asiko taa wa
yii ki i sakoko to dara fun Abayomi Arabambi, alaga awon egbe oselu lapapo iyen
IPAC, to tun je alaga fegbe oselu Labour nipinle Ogun, rara nitori bawon omo egbe se
daa duro, ti won si ni yoo tun koju igbimo to n ri iwa ibaje ninu egbe naa.
Nibi ipade
egbe naa to waye ni adugbo Akin Olugbade niluu Abeokuta legbe naa ti gbe igbese
yii nitori awon esun ti won ka sii lese ati bo se pe ipade egbe ti ko yoju, ti
won lo tun ni ipade naa ko tun waye mo leyin tese awon omo egbe ti pe.
Ohun taa gbo
ni pe lojiji ni Arabanbi gbe atejade kan sita lori ero ayelujara pe ipade naa
ko ni le waye mo nitori emi oun ko de, awon kan lepa emi oun.
Sugbon awon
omo egbe ko ri tie ro ti won fi tesiwaju ipade mo, won ni alaga won yii ti mo
pe o lawon ebo leru lo se paro pe awon kan fee pa oun.
Olufẹmi to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu Better Nigeria Progressive
Party, to tun jẹ alaga awọn to pẹtu si aawọ ninu ẹgbẹ naa, ti wọn ṣẹṣẹ yan
sọ pe "Ninu ipade ta a ṣe lonii, gbogbo ọmọ ẹgbẹ lo wa nikalẹ, tonikalu si
fi oriṣiriṣi ẹsun kan Kọmreedi Arabambi lori pe ko jẹ kawọn ọmọ ẹgbẹ ri nnkan
to n lọ ninu ẹgbẹ, to si tun n pa irọ, oun la ṣe fẹnuko pe ka tare ẹ si ọdọ awọn
to n ṣewadii, iyẹn Discplinary committee.
"Oriṣi iwe ẹsun mẹta ọtọọtọ ni wọn mu wa, paapaa
ninu ẹgbẹ tiẹ to n ṣe, eyi to jẹ Labour. a ko si le fi ina sori orule sun, ki
ẹgbẹ IPAC to o le lọ siwaju, a gbọdọ gbe ilana kalẹ la ṣe fẹnuko pe a fi ki
Arabambi lọọ jokoo sile naa, lati le ṣewadi awọn ẹsun ti wọn fi kan an yi.
"Emi ro pe arifin nla ati aikanikun ni igbesẹ ti
Arabambi gbe lati sọ pe o da ipade nu. Alaga funra ẹ lo pe ipade lori awọn
kọmiti ti a fẹ ẹ yan lonii, to si bu ọwọ luu pe ka maa bọ. A ti pejọpọ lati
bẹrẹ ipade ko too bẹrẹ si i fi atẹjiṣẹ ranṣẹ pe oun ko fẹẹ wa nitori pe awọn
kan n fi iku wa oun kaakiri. Bibeli sọ pe bi iwọ ba ṣe rere, ara ki o a ya ọ
bi.
"Idibo ti kọja, o si ti lọ, a si ri i pe oriṣiriṣi
ọna ati igbesẹ ti ko tọ ni Arabambi gbe, ta a si pe ipade pe ko wa a ṣalaye ara
ẹ. Ile gbọrọmiro nile ẹjọ, iwe ofin wa fun wa to gbe wa lẹyin, ko gbiyanju lati
lọ"
Bakan naa nigba toun naa n sọrọ, Kọmureedi Bọla Oyedele
to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Party of Nigeria, PPN nipinlẹ Ogun sọ pe
"Bi alaga ta a ṣẹṣẹ yọ yi ṣe loun sun ipade siwaju lo da awuyewuye silẹ. Aggọ
mẹwa lo yẹ ka bẹrẹ ipade, ta a si ti pejọ, ko da ti amugbalẹgbẹ Kọmureedi
Arabambi naa tun wa nibẹ, lẹyin bi i wakati kan lo to o ṣẹṣẹ fi atẹjiṣẹ ranṣẹ
si wa pe oun ti sun ipade siwaju.
"Bi gbogbo laga ẹgbẹ oṣelu patapata ba wa nibi kan,
ti ẹnikan ṣoṣo ba wa sọ pe ẹmi oun wa ninu ewu, o tunmọ si pe awọn ara ipinlẹ
Ogun ko si labẹ aabo to peye niyẹn, a si gbọdọ jẹ kawọn eeyan mọ pe aabo to
peye lo wa nipinlẹ Ogun ta a wa yi.
"To ba fẹ sun ipade siwaju, o yẹ ko ti fi to wa leti
lati bi i wakati mejidinlaadọta (48hours) tabi wakati mẹrinlelogun (24hours).
Ṣe lo foju di gbogbo wa patapata, nitori pe alaga ẹgbẹ oṣelu kọọkan ni gbogbo
wa, ta a si pawọpọ lati fi sibẹ, ko yẹ ko ri bẹẹ."
Ninu ọrọ ti alaga fidihẹ ti wọn yan, Alaaji Mọshood
Adeṣhina ni "Ko si nnkan to jọ pe ki ẹnikan pade eeyan kan nile ẹjọ nitori
pe a ti yan igbimọ nitori pe awa ta a wa nibi ipade yi pọ ju awọn ti ko si nibẹ
lọ, ti ofin si wa fun un. Ki i ṣe pe wọn yọ Araba,bi lailai, fungba diẹ ni wọn
fi sọ pe ko ṣi lọ jokoo sile naa, nitori pe alaga ko le wa lori ipo lasiko ti
wọn n ṣewadi lọwọ
"A tẹle ofin ati ilana to de wa. A ko le wa bayii ki
ẹgbẹ ma ni olori lo mu kile panupọ lati yan mi gẹgẹ bi alaga fidihẹ."
Nigba to n tako ẹsun ti wọn fi kan an, ati bi wọn ṣe yọ
ọ, Kọmureedi Abayọmi Arabambi ninu ọrọ sọ pe awada kẹrikẹri ni wọn n ṣe nitori
pe ko sẹni to to bẹẹ lati yọ oun nipo, nitori pe ipade ti wọn ṣe naa, oun loun
pe e, toun si tun ti sun un siwaju pe ipade naa ko le waye mọ.
Arabambi sọ pe, nnkan toun mọ daju ni pe Ọmọba Buruji Kaṣhamu ati Ọmọba Dapọ Abiọdun ni wọn wa nidi igbesẹ tawọn ọlọtẹ ninu ẹgbẹ IPAC
naa gbe, nitori pe ọpọ igba lawọn mejeeji yi pe oun pe koun wa a gba owo lati
le yọwọ kuro ninu ẹjọ Tribunal toun pe.
O tun sọ ninu ọrọ rẹ pe ọgọrun miliọnu naira ni Omooba Buruji Kaṣamu fi n bẹ oun lati yọwọ ninu ẹjọ naa, ti Omooba Dapọ Abiọdun naa si n fi obitibiti
owo lọ oun, lati le pana ẹjọ to n lọ lọwọ ni Tribunal.
Siwaju si i ninu ọrọ rẹ, o ni "Loootọ, emi ni mo pe ipade yi, ti mo si fi lẹta ranṣẹ si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ,
ṣugbọn nigba ti mo gbọ pe ṣe ni wọn fẹẹ pa mi, lo jẹ ki n sọ pe ka sun ipade
naa siwaju. Ọgbẹni Olufẹmi Oluṣẹgun to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu BMPP ati Ọgbẹni
Mọshood Adeṣhina toun jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu Mẹga ni wọn gbimọ lati gba ẹmi mi
lonii, ti mo si sa asala fun ẹmi mi."
No comments:
Post a Comment