Aisanwo ati aini idanilekoo mu ifaseyin ba idagbaske ise iroyin-Oladunjoye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 24 April 2019

Aisanwo ati aini idanilekoo mu ifaseyin ba idagbaske ise iroyin-Oladunjoye

Tunde Oladunjoye


Okan lara agba-oje nidii ise iroyin,Tunde Oladunjoye, ti so pe lara idojuko ti ko je ki idagbasoke de ba ise iroyin lorileede yii airowo osu san dede fawon osise iroyin ati aini idanilekoo gba.

Lojo Isegun, Tusidee, ose yii ni okunrin naa soro yii lakooko to n se idanilekoo eyi egbe to n je Association of Communication Scholars and Professionals of Nigeria (ACSPN), tie ka ile Yoruba sagbateru e, eyi to waye ni eka imo ofin logba ileewe giga  yunifasiti Crescent, Abeokuta, nipinle Ogun. 

O fikun oro e pe bawon to nileese iroyin se kuna lati maa sanwo to ye fawon osise won topo won si tun je owo osu
ko je ki itesiwaju de ba ise naa to s n je tawon ti ko mo nipa ise naa foju abuku wo ise naa.

Oladunjoye to je olupolongo fegbe oselu APC nipinle Ogun tun salaye pe lara awon idojuko to tun mu ifaseyin ba ise naa bi ko se si idanilekoo to peye fawon ti won sese n bo nidii ise naa.


O ni bi won ba fee ki idagbasoke ba ise iroyin, idanilekoo gbodo maa waye fawon to n sise naa, eyii yoo je ki oye ise naa ye awon to nifee sise iroyin.


Okunrin naa tun so pe "Ni ero temi,idanilekoo ironilagbara je eyi to dara, to si je igbese to lagbara, nitori okan lara nnkan taa kuna lode oni in ni, paapaa julo nipa ise iroyin. Ko si ise naa laye yii to ba fee ni ilosiwaju ti ko ni mu idanilekoo, ilaniloye atawon nnkan mii in lawujo ni pataki”.

O wa daa labaa pe ki iru ironilagbara idanilekoo ko maa waye nigba de igba, ki won si maa gbe e jade lakooko sakoko leyi ti yoo ran awon to n bo lojo iwaju ti won nifee si ise yii.No comments:

Post a Comment

Pages