Dapo Abiodun |
Gomina
tuntun ti won sese dibo yan nipinle Ogun, Omooba Dapo Abiodun ti se ikilo fawon
omoota atawon omo egbe okunkun nipinle naa lati jawo tabi fi ipinle naa sile
nitori isakoso oun ko ni faye gba won.
O
soro yii lakooko to sabewo siluu Ifo, nibi to ti loo ki won fun ibanikedun awon
ti won padanu emi won nibi wahala to waye lojo Aiku, Sannde.
Gomina
ti yoo gba ipo losu to n bo naa fikun oro e pe oun mo pe gbogbo awon olugbe
ipinle Ogun ni won fee alaafia, o ni enikeni towo ba te pelu ohun ija oloro ni
won yoo fi jofin.
Lara
awon ibi ti Dapo Abiodun tun sabewo de ni ofiisi asoju-sofin fun ekun
Ifo/Ewekoro, Onarebu Ibrahim Isiaka ati ti igbakeji olori ile asofin nipinlee
Ogun, Onarebu Olakunle Oluomo ti won dana sun moto e marun un lojo naa.
Dapo
Abiodun wa sapejuwe isele naa gege bi eyi to buru paaaa bawon eeyan meji se
padanu emi won, o wa ro awon araalu lati maa ni aanu omonikeji won.
Gomina
tuntun naa tun so pe “Fun gbogbo awon to lo anfaani nnkan to sele naa lati da
wahala sile la o rii pe a fi won jofin. A ko le faye gba iwa janduk tabi egbe
okunkun ati oni iwa ibaje laaye lati ba ipinle yii je.”
“Mo
lo akoko yii lati kilo fawon to ba wa ninu egbe okunkun pe asiko ti to fun won
lati jawo bi beeko won yoo je iyan won nisu’
Bakan
naa ni Gomina t n bo naa tun seleri fawon odo to ba fawon iwa janduku sile lati
se nnkan gidi fun won leyin ti won ba se ibura foun lojo kokandinlogbon, osu to
n bo yii.
No comments:
Post a Comment