Oluwo tilu
Iwo, Oba Dokita Abdulrasheed Adewale Akanbi, ti so pe isokuso ni itan tawon eya
Igbo, eyi to jade lenu Ohaneze Indigb pe abigbeyin ni Oduduwa to da ile Yoruba
sile je fun omooba igbo, o ni ko le ri be rara, itan ti ko fese mule ni ti won
fee fi da wahala sile ni.
Ninu atejade
kan ti Ali Ibraheem to je akowe eto iroyin fi sita loruko Oba naa fi sita, lo tun ti kilo fawon to le
maa pa itan to le maa da wahala sile pe bawo ni Oduduwa se le je abigbeyin
Igbo.
Oba Adewale
Akanbi tun so siwaju pe bawon Igbo ba fee pa itan, o ye ki won se iwadii daadaa
ki won to maa so, ko ye ki won maa paro itan ti ko sele tabi so nnkan to le da
wahala sile.
O ni
latidaye ni won ti so ninu itan pe Oduduwa lo sokunfa ade tawon oba n de
kaakiri agbaye, o si ti wa ko to di pe won seda Igbo, o wa beere pe bawo ni o
se le je omooba feni too baa?
Oba naa
salaye pe ohun manigbagbe ni itan je ti ko se fi sere nitori oun ni opa imole
fojo iwaju. O ni ade tawon n de yii agbara emi kan ni ti ko se fojudi. Oduduwa
lo ni o si gbe wa nitori idi eyi ko sona tawon ko fi ni maa dabobo o.
A o ranti pe
lenu ojo meta yii ni Ohaneze Ndigbo bu enu atelu oro ti Ooni tilu Ile-Ife, Oba
Enitan Adeyeye Ogunwusi so pe Ile- Ife ni eya igbo ti jade wa.
O ni Oduduwa
abigbeyin to tun so pe o je okan lara omooba Igbo to gbakoso Ile- Ife sugbon ti
Yoruba so di Olorun won je alagbara, o tun ni Yoruba ko lati so ede Igbo nigba
naa, nitori e ni ko se fi bee si iyato ninu ede Igbo ati Yoruba.
Oba naa wa
ro gbogbo omo Naijira lati wa ni isokan ki won year fun nnkan to le pin won
niya pelu ileri pe gbogbo ona loun yoo fi maa wa igbega Oduduwa.
No comments:
Post a Comment