Alagba Akintayo Sanya |
Sannde, Ojo
Aiku, ojo ketadinlogbon, osu yii ni soosi ijo Eri Atunse, ogba majemu to wa ni
ilu Mushigogo legbe Eko Akete, nijoba ibile Ibeju Lekki yoo sajodun onibeta.
Gege bi atejade
ti Alagba Akintayo Micheal, Baba Wolii fi sita, ojo naa ni won yoo se ajodun
asorodayo, eyi ti won ti bere isoji ati awe e lati ojo mejilelogbon seyin.
Bee ni isin
idupe irinajo majemu ati ayajo Babanla mejila. Lati ojo ketadinlogun, osu keta
ni won ti bere orisirisi eto okan-o-jokan fun ti ajodun oba asorodayo todun
yii.
Lale ola,
Satide, ojo Abameta ni aisun ayajo Babanla mejila yoo waye ni soosi naa bere ni
deede aago mokanla ale titi di aaro mojumo.
Nibi ajodun
ojo Sannde ni Alagba, Oba S O Oyelami yoo ti foro Olorun boa won eeyan lojo.
Awon ojise Olorun ti won fiwe pe ni won yoo wa sise iyanu, bee ni awon olorin
emi ko nii gbeyin.
Baba Wolii
ti wa mu da awon eeyan loju pe ko seni to wa ti ko nii mu ayo loo sile nitori
oba asorodayo ti gunle sinu ijo naa.
No comments:
Post a Comment