Gomina
tuntun ti won sese dibo yan nipinle Ogun, Omooba Dapo Abiodun ti
muu da awon alase ati akekoo ileewe olukoni Tai Solarin,to wa ni Omu- Ijebu
loju pe oun yoo wa ona abayo si isoro to n dojuko won loju ese toun ba gbakoso
ijoba lojo kerindinlogbon, osu to n bo.
O soro yii
lakooko tawon osise ileewe naa, eyi ti Ogbeni Daniel Aborisade saaju won loo sabewo sodo re nile e to wa ni Iperu Remo
lojo Furaidee.
Idi tawon
osise ileewe naa fi sabewo sodo Dapo Abiodun ni lati ki I ku oriire fun bo se
jawe olubori fun ti ibo gomina ti won di laipe yii, bee ni won tun lo akoko naa
lati so awon isoro to n dojuko won ninu ogba naa.Eyi ti won ti yi oruko ileewe
naa pada si Augustus Taiwo.
Won tun so nipa bi won ko se sanwo osise atawon owo ajesile, bee
ni won ni ijoba to wa lode yii tun je won ni owo ifeyinti, owo alajeseku atawon
ipenija mii in to n dojuko won ninu ogba ileewe naa.
Bee ni awon asoju naa tun bebe pe ki won gbe igbimo kan dideT ti
yoo wa se iwadii lori nnkan tawon menuba pe o n dojuko awon ni ogba lleewe naa.
Gomina tuntun naa wa seleri pe gbogbo idojuko to n doju ko won
lawon yoo sise le lori, pelu idaniloju oun yoo sabewo sileewe naa toun ba ti
gbakoso ninu osu karun odun yii.
No comments:
Post a Comment