Sunday Olaposi Oginni, to je akowe igun kan ninu egbe oselu
Labour, nipinle Ogun, ti so pe ise adase ni alaga egbe naa ni igun keji,
Abayomi Arabanbi, je lori atejade to gbe jade lori isokuso ti won lo so si
igbakeji aare lorileede yii, Ojogbon Yemi Osinbajo, won ni ko seni to ran an
nise to je.
Ninu atejade ti okunrin naa fi sita lojo Aje, Monde, loruko egbe
oselu naa lo ti so pe ipo ti egbe naa wa ninu igbimo to n gbo ejo ibo gomina to
waye ni lati bowo fun ofin.
O fikun oro e pe ejo ti egbe naa pe ti nomba e je
EPT/OG/GOV/02/2019 lawon yoo sise lee lori debi to lapeere.
Lojo Aiku, Sannde, ni Abayomi Arabambi, ti koko gbe atejade kan
sita nibi to tii tabuku igbakeji aare orileede yii, Yemi Osinbajo pe oun lo wa
nidii bi won se fofin de igbimo to n gbejo lori ibo gomina ti Adajo Chinwe
Onyeabor je asaaju won.
Sugbon ti Oginni ko je koro naa fale to fi fun ni esi pe ko seni
to ran an nise. O so pe awon tawon je ojulowo egbe oselu Labour fee karaye mo
pe awon ko lowo sii ati pe ise tawon oga e ti won sanwo fun un ran an lo n je.
O ni ojulowo oloye egbe naa yoo se ipade lojo Isegun, Tusidee,
nibe lawon yoo ti soro lori igbese tawon yoo gbe lori oro ileejo giga apapo.
O ni awon nigbagbo ninu ijoba tiwa-n-tiwa too ni se pelu ofin,
awon si ti setan lati se gege bi ofin ba se so.
No comments:
Post a Comment