Awon towo te pe won foruko Dapo Abiodun lu jibiti |
Lai tii pe osu kan tawon ara ipinle
Ogun dibo yan, Dapo Abiodun gege bi gomina ipinle Ogun, owo awon olopaa ipinle
Ogun, ti te awon ore meji kan, Taiwo Edun ati Hasaan Jimoh lori esun pe won n
foruko okunrin to sese wole naa lu awon eeyan ni jibiti nigboro.
Gege bi a se gbo, bi won se kede pe
Dapo Abiodun ti di gomina ni won lawon kan ti wona lati maa foruko okunrin naa
lu awon eeyan nijibiti, se ni won lawon towo te naa so pe Dapo Abiodun ti so
fawon pe kawon bere si ni gbawon eeyan sise labe ileese kan ti won sese fee da
sile, eyi ti won pe ni fifo ipinle Ogun mo tawon oloyinbo pe ni “Keep Ogun
State Clean Corps”
Won ni se lawon eeyan yii tun se
ipolowo e ti won pe akori e ni “Dapo Abiodun Environmental Task Force”. Won so
o debi pe egberun mewa awon osise ni won fee gba, to tumo si pe eedegbeta
nijoba ibile kookan nipinle Ogun, Eni to ba nifee sise naa ni won ni yoo san
egberun meta naira.
Agbenuso awon olopaa nipinle Ogun,
Abimbola Oyeyemi, salaye pe bi Onarebu Remmy Hassan, to je agbenuso fun Dapo
Abiodun se pariwo sita pe Dapo Abiodun ko mo nnkan kan nipa awon eeyan naa ati
pe won fee maa fi lu awon araalu nijibiti lo mu kawon tete gbe igbese tawon si
topinpin awon to wa nidi ibaje naa.
O ni ase ti komisanna tuntun nipinle
naa, Bashir Makama, pa lo je kawon ma foro naa fale to si je pe laaarin iseju
merinlelogun tawon gbe igbese lo mu kowo te Edun atore e, Jimoh.
Oyeyemi salaye pe orisirisi leta ti
won ko sawon ileese ati aso ise won ti won ko “Keep Ogun State Clean” lawon ri
gba lowo won. Ni bayii, Komisanna awon olopaa, ti wa pase pe ki iwadii bere ni
kiakia bee lo tun so pe gbogbo awon yooku ti won jo n sise naa ni ki won mu
patapata.
Bakan lo tun gba awon araalu nimoran
lati gbakiyesi fi fawon eeyan lowo lati bawon wa ise nitori opo won lo je onijibiti tutu.
No comments:
Post a Comment