Ka ni Arakunrin kan, omo odun metadinlaadota, Balogun Ayodele,ba mo pe igbejo to loo yii maa koba, o se e se ko ma lo tabi ko wa ise mii in se lojo naa, sugbon nitori pe o ti n se tipe, o si ti wo o lara lo je ko wa latimole awon olopaa bayii.
Lojo keji, osu yii, la gbo pe owo te
Balogun ti won fesun kan pe ayederu agbejoro ni niluu Ilaro lakooko to loo
gbejo ro fenikan ni kootu majisireeti to wa nibe.
Bi won se ni okunrin naa n se niwaju
adajo nigba ti ejo naa n lo lowo lo mu ki ara fu adajo to n gbejo naa lowo, to
si beeere awon ibeere to je mo awon loya lowo sugbon tokunrin naa n wo bi ole
inu ireke.
Adajo naa ko foro e fale rara, ko je
ko kuro niwaju e gan-an to fi ranse pe awon olopaa to wa ni Ilaro pe ki won wa
mu arufin ayederu loya naa, loju ese ni won si ti mu loo si tesan won.
Bi Balogun se ri pe akara tit u sepo
foun, se lo ni kawon olopaa se oun jeje to si jewo fun won pe loooto oun ki i
se loya, toun ko si kose e rara sugbon oun ti n wa si kootu tipe toun si maa n
se bi agbejoro toun fi lu won ni jibiti.
Nibi ti iwadii ti n lo lowo, ni okan
lara awon to n so awon elewon ti so pe kositoma daadaa ni Balogun je sawon
nitori pe laipe yii lo sese kuro logba ewon leyin to lo osu mefa fun iru esun
bee.
Ni bayii, komisanna awon olopaa,
Bashir Makama, ti pase pe ki won tete gbe okunrin naa lo sileejo,leyin ti won
ba ti pari iwadii e. Bee lo tun se ikilo pe ipinle Ogun ko ni faye gba enikeni
to pinnu lati mu iwa ibaje ni Pataki ninu aye e.
No comments:
Post a Comment