Egbe oselu Labour fee gba eedegbeta milionu lowo ajo INEC atawon oludije oloselu kan - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 8 April 2019

Egbe oselu Labour fee gba eedegbeta milionu lowo ajo INEC atawon oludije oloselu kan



Ona mii-in ni egbe oselu Labour tun gba yo lori bi ajo eleto idibo iyen INC se yo oruko oludije gomina won ati ami idanimo egbe naa kuro ninu ibo to waye lojo kesan-an, osu to koja yii, ile ejo giga tijoba apapo to wa niluu Abeokuta, ni won tun ti gba lo bayii lati gba eedegbta milionu naira lori asise naa.

Gege bi a se gbo, awon ti won pe lejo naa ni oga agba fajo INEC nipinle Ogun, AbdulGaniy Raji, egbe oselu All Progressives Congress, APC ati oludije won fun ipo gomina, to tun wole ibo naa, Dapo Abiodun.
Awon yooku ni egbe oselu Allied People’s Movement, APM ati oludije gomina won, Adekunle Akinlade. Ati egbe oselu African Democratic Congress, ADC ati oludije won, Gboyega Isiaka.
Ninu iwe ipejo ti nomba e je FHC/AB/ FHR/44/19, ni Ogbeni Sunday Oginni, to je akowe apa kan ninu egbe naa nipinle Ogun atawon meji mii in, Ibrahim Babalola ati Segun Oloyede ti won je alaga egbe nijoba ibile Abeokuta South ati Odeda fowo si ni won ti pe ejo naa.
Ninu iwe ipejo naa ni won ti ro ileejo lati pase pe bi won se yo oruko egbe oselu naa kuro ninu iwe ibo gomina to waye naa je eyi ti ko bojumu.
Awon olupejo naa wa n fee ki ileejo giga tijoba apapo lo ase e lati fagile ibo naa labe ofin eka ogoji todun 1999 ninu iwe ofin ile wa.
Bee ni won tun be ileejo lati pase pe kawon ti won pe lejo naa san eedegbeta milionu naira fawon asise ti won se lati ba nnkan je fegbe oselu Labour.

No comments:

Post a Comment

Pages