Agidi ati afojudi lo sakoba fun ijoba Amosun- Muyiwa Oladipo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 9 April 2019

Agidi ati afojudi lo sakoba fun ijoba Amosun- Muyiwa Oladipo


Basorun Muyiwa Oladipo

Komisanna foro asa ati irinajo igbafe ni Bashorun Muyiwa Oladipo, Gomina Ibikunle Amosun lo si n ba sise po, ko to di pe okunrin naa kowe fipo e sile pe oun ko baa sise po mo. Okunrin naa gba wa lalejo ni ofiisi e, nibi to ti ba wa foro-jomi-toro-oro nipa idi ti ko se ba oga e yii sise mo atawon nnkan mii in. Awon nnkan to ba wa so niyii.

Idi ti mi o fi baa Amosun sise papo mo

Ko si nnkan meji ti mo fi kowe fipo sile gege bi komisanna foro asa ati irinajo afe nipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun lo ko ju pe ina wa ko wo mo.

Nitori awon Yoruba soro, won ni bi oni se so pe yoo ri, ola le maa ri be lo difa fun babalawo to n fi n difa oroorun. Ina ko wo mo laarin emi ati oga mi tele, Gomina Ibikunle to fee ko igba wole bayii. A si mo pe lojo ojo kan, ona lo jin, eru ni baba.

Emi ni mo da ayeye odun ilu lilu sile

Mi o ri ti ayeye odun ilu lilu ti won fee se yen ro pe mi o ni si nibe sugbon mo fee sare so kinni kan nigba ti awon orisa n bo lojo si, Ogun lo lana tawon yooku tele.

Emi ti lana bayii, kawon yooku maa tele lo ku. Mo ti n gbo orisirisi ariwo lotun losi paapaa julo awon to wa loke ti won so pe awon lawon da odun ilu lilu sile.

Mo fee akoko yii so fun gbogbo aye atawon to n ka oro mi pe emi Muyiwa Oladipo ni Olorun fi ase ogbon yen fun lati sagbekale e fun ilosiwaju ipinle Ogun lori oro asa ati igbafe.

Nigba taa da sile nigba naa ti Gomina mu wa kuro nileese ti mo wa tele iyen oro ijoba ibile ati oye jije, loooto a mo nnkan to yii ka to fi gbe wa kuro nibe sugbon iyen ki i soro ojo oni, ojo iwaju ni.Sugbon ero okan won ni pe bayii lo se maa ri nibi ti won tun gbe wa lo, amo won gbagbe Olorun ni. Mo tun wa de be, mo wa gbe ogo ipinle Ogun yo nipa odun ilu lilu.

Won ko mo pe o le yori si rere nigba naa, Gomina mi to fee kogba wole yii, Ibikunle Amosun ko nigbagbo pe odun ilu lilu le yori si rere. Emi ni mo so o, mi o yo so. Odun naa ni won wa so di Pataki, oro won dabi oro inu Bibeli to so pe okuta ti omole ko ti, lo wa di origun ile.


Emi o kabamo pe mi o ni bawon kopa.

Abamo ke, rara o, bi mi o ba si laye n ko, se won ko nii se ni, Ohun ni mo se pe ninu ohun gbogbo ka sa maa dupe, ni odun metalelogoji ni won ti da ipinle Ogun sile.

 Mo fi ara mi we Josefu ninu Bibeli, se e mo pe ala lo gbe de ibi to de, nigba to wa ni kekere, to la ala pe awon igi mokanla duro, won n teriba fun toun, awon egbon e binu si, won ta si oko eru, sugbon ngba ti ala naa yoo se, o di olori nile Egypit, bo se maa ri niyen fun emi Muyiwa omo Oladipo.

Gege bi mo se n so tele, odun metalelogoji taa da ipinle Ogun sile, e ma gbagbe akoko kan naa la jo maa n se ojoobi papo, iyen ojo keta, osu keji, ko seni to ro oro odun ilu, odun ayan ti Muyiwa fi de ibe yen. Asiko si to ni Olorun fi gbe si wa lori, laa fi gbe sile.

Nigba taa n se nigba naa lohun, a ko fe ki ijoba ko lowo ninu e, nipa gbi-gbo-wo- sile, nnkan taa kan fe lodo won ni ki won fun wa ni akoko ati agbegbe taa maa lo.

Nitori odun ilu lilu, se lo ye kawon ileese nla, ko maa gbowo sile fun wa lati maa fi se. Inu mi dun pe odun kerin ree, ti won fee se, yoo soro fun ijoba to n bo lati paare, nitori gbogbo onikaluku lati orileede yii ati ni Africa ni won ti n wa kopa.

Ko sibi tijoba Dapo Abiodun ba gbe mi si  

Mo fee so fun yin pe ko sibi tiijoba Dapo Abiodun baa gbe mi si, ti e ko ni ti ri owo mi ati ti Olorun, nitori mo fi gbogbo enu so ni wakati yii pe omo ologo ni mi. Ibi ti elegede mi ba fowo ba, didun ni yoo maa dun, a ran mi si ipinle Ogun lati se oriire, e lo wo mi lodo Baba Osoba, nigba ti mo fi je olori ile igbimo asofin, e e lo woo, nigba ti mo tun kuro nibe, e lo woo.

Nigba ti mo si je komisanna foro oye jije ati ti ijoba ibile pelu ibi ti mo tun sese kuro nibe yii, ko seni to le fowo ro mi seyin, etanu ati ilara  lo kan maa n po nibe,  amo mo dupe.

Igbelewon awon komisanna ti mo ti se

Bi a ba ni ka so tododo, ni iileeese oro ijoba ibile ati oye jije ti mo ti koko je komisanna, owo wa nibe loooto sugbon iyi ko fi bee po. Sugbon ni ti asa ati irinajo igbafe iyi po nibe repete,owo sit un wa nibe amo mo dupe pe awon ise ti mo se lawon ibi mejeeji naa ko nii pare lailai.

Emi ko ri oro APM ro latile

Mo ti maa n so tipe pe latigba ti ipolongo ibo ti bere ni emi ko ti ri oro APM ro, ti mo si mo pe egbe oselu APC lo maa wole, nitori eni to ba n tele itan ipinle Ogun latile yoo ti mo pe awon omo ipinle Ogun yato. Emi naa mo pe o maa n soro latigba ijoba lowo eni to ba wa lori ipo. Amo ise ti Olorun ti pari ni.

Dapo Abiodun maa n soro kan ti a ba wa lodo e, a so pe to ba je imo ti eeyan ni oun ko ni wole sugbon to ba je ti Olorun ni, oun maa wole, nitori oun mo pe Olorun ju awa eda lo.
 Eyi lo si je ki emi naa mo pe Olorun mo on mo fee ki Dapo Abiodun di gomina ipinle Ogun ni, pelu gbogbo awon nnkan tawon ti foju ri lakoooko ipolongo.

Loooto ni Gomina mi to fee kogba wole laipe yii ri owo naa, owo ijoba lo si n na, gbogbo araalu lo si letoo lati gba owo naa sugbon won mo eni ti won maa dibo fun.

Mo tie gbo pe Gomina mi yii n so fawon tie pe awon ko sise awon daadaa to lo je ki awon fidi remi ninu ibo naa.

Amosun fojudi awon to wa ni Ogun East

Mo fi gbogbo enu so pe afojudi wa lara nnkan to n se Gomina mi to fee kogba wole yii, niitori aimoye igba lo maa n so nigba ta ba wa ni ipade pe ko si nnkan tawoon fee fi ibo Ogun East se, tawon ba ti mu Ogun Central, tawon pin ibo Yewa pelu GNII, tawon si mu Ado- Odo- Ota, ko si nnkan tawon fee fi ti Ogun East se mo, awon kan le mu eyo kan soso niibe, nnkan to si mu ki Amosun so bee ni pe erongba e ni pe PDP lo maa wole niibe.

Sugbon nigba ti Olorun maa fi ajulo han, nigba ti esi ibo maa jade Ogun East yen gan an ni APC ti wole ju. Mo tun fi akoko yii so pe latigba ti won ti n dibo nipinle Ogun, ibo yii ni akoko to je pe ko ni si ija tabi wahala ti gbogbo e loo nirowo-rose.

Pelu gbogbo ariwo won lati fi ko awon araalu laya  fun ibo naa, awon eeyan ko rii ro, won jade sita lati wa seto won.

Ileejo ti APM n lo.

Mo gbo pe won lawon APM so pe awon loo sileejo lori awon ibikan ti won ko ti wole pe won ja nibe, se awon ibi ti won lawon ti wole, won ko ja nibe, ko si wahala, won maa ba awa naa nibe.

Amoran mi fun Dapo Abiodun

Awon nnkankan wa ti mo fee ki Dapo Abiodun se ninu ijoba e, akoko ni ko fi ti Olorun siwaju ohun gbogbo to ba fee se, eleekeeji ni ko fi tawon agbaagba se ati pe ko ri ijoba e gege bi ajose ki i se adase.

Nitori lara nnkan to gbe Amosun subu ninu ijoba e to n kogba wole ni pe ki i fee gbamoran telomii in, bi a ba wa ninu ipade, o maa n ri gbogbo awa taw a pelu e gege bi eni ti ko ni opolo ti ko ni ironu, ayafi nnkan to ba fee se nikan, iyen ko si ri be, agidi okan yii si je nnkan to mu ifaseyin ba ijoba e.

A gbo ninu itan pe nigba ti Oloye Obafemi Awolowo ba n se ipade pelu awon omo egbe e, gbogbo won lo maa n fee ki won soro pata, nigba ti won ba sib ii lere pe ki lo de to fi gba awon omode laye lati soro, nnkan to maa n so nip e ninu oro omode nigba mii in, ogbon to maa n se mulo maa wa nibe.

O da mi loju pe Dapo Abiodun yoo se daadaa ninu ijoba e nitori eni to ni iberu Olorun, to si ni ero rere fawon eeyan e.
 .





No comments:

Post a Comment

Pages