Lekan Old Skool fee se sayeye odun kokandilogun to n korin - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 3 April 2019

Lekan Old Skool fee se sayeye odun kokandilogun to n korin


-Bee ni yoo tun se ifilole kaseeti tuntun

Lojo Aiku, Sannde, tii se ojo keje, osu kerin, ni gbajumo olorin juju nni, Lekan Fasola, topo awon ololufe e mo si Old School yoo se ayeye onibeji niluu Abeokuta.

Gege bi a se gbo, lojo naa ni okunrin to da egbe olorin Lekson Musician Band sile yoo se ayeye odun mokandinlogun to bere si nii korin tawon aye si n gba tie, bee naa ni yoo lo anfaani ojo naa lati fi se ifilole ikojade kaseeti orin tuntun eyi to pe akole e ni New Glory iyen Ogo tuntun.

Gbongan BOC to wa ni Housing, Oke- Ata, niluu Abeokuta ni ayeye naa yoo ti waye bere ni deede aago mejila osan. Lara awon to fiwe pe lojo naa ni Oloye Matthew Adeoye, oun ni baba ojo naa, nigba ti Arabinrin Ganiu yoo si je iya ojo naa pelu.

Awon to tun n bo lojo naa ni Oluseye Arowolo toun yoo je alaga pataki, olufilole pataki ni Oloye Akeem Akinsola, Okanlomo ile Egba.Alaaja Fausiat, to ni ile ounje Madojutimi oun ni alaga obinrin. Atawon eeyan pataki yooku ti won fiwe pe bee naa lawon olorin lorisirisi naa yoo tun da awon eeyan lara ya lojo naa.


No comments:

Post a Comment

Pages