Gomina fegbe awon apapo olorin PMAN nipinle Ogun,Saidi Bolomope tawon ololufe e mo si Landoma ti so pe inu irepo lawon wa ninu egbe naa ati pe ko si wahala kankan laarin won.
O soro yii
lakooko to n ba oniroyin wa soro lori aseyori e lenu igba to di adari egbe naa.
O so pe inu oun dun pe ko si eleyameya kankan mo ninu egbe awon olorin, tawon
si n bara won se po.
Okunrin naa
so pe fun igba akoko, egbe awon ti ni ofiisi nla, eyi to wa ni Akin Olugbade,
niluu Abeokuta. Nibi tawon ti n se ipade papo.
O ni ohun iwuri
lo je foun pe latigba tawon ti ni ofiisi naa lawon omo ti n sapa iranlowo lati
je ki ofiisii naa dun wo, ti won si n ra awon nnkan sibe.
Landoma tun
salaye siwaju pe bo tile je pe erongba awon kan ni pe omo onifuji ti ko kawe ni
won fi se gomina egbe naa sugbon oun dupe pe Olorun ran oun lowo.
O ni ki i se
pe oun ko kawe sugbon iwonba toun ka tun ran oun lowo lati fi le tuko egbe naa
gege bi onifuji akoko ti yoo koko je gomina f, egbe apapo awon olorin nipinle
Ogun.
Bakan naa ni
Gomina fawon olorin naa tun lo akoko naa lati ki gomina tuntun nipinle Ogun,
Dapo Abiodun ku oriire lori bi won se dibo yan an gege bi gomina.
O wa gbadura
pe Olorun yoo fun lemi ogbon ati oye lori gbogbo nnkan to ba dawole lati fi
tuko ipinle Ogun. O lo akoko naa lati so fun Dapo Abiodun lati ranti egbe apapo
awon olorin, PMAN ninu ijoba.
O ni o se ni
laaanu pe opo awon ijoba to ti n je, to fi mo eyi to wa lode ni won ki i ranti egbe
PMAN, ti ko si ye ko ri be nitori o ni anfaani tawon naa n se lawujo.
No comments:
Post a Comment