Lojobo, Tosidee, ojo kokanla, osu
yii ni ayeye isinku iyawo oludasile ijo Ile isura Olorun iyenTreasure House of
God, Pasito Oluwayemisi Senfuye yoo bere.
Gege bi atejade ti Ogbeni Adeniyi
Adeloye, to je oluranlowo nipa iroyin fun Pasito Adeseye Senfuye, fi sita lo ti
so pe ojo merin ni won la sile fojo naa.
Isin aisun ni yoo koko waye lojobo,
Tosidee, nile ijosin Treasure House of God, Quarry Road, Abeokuta, bere ni
deede aago marun- un irole.
Isin pataki lati fi saponle oloogbe
naa ni yoo waye lojo Eti, Furaide, ojo kejila nile- ijosin yii bakan naa, aago
mesan an aaro ni isin naa yoo ti waye.
Leyin ti won ba pari isin naa tan ni
won yoo loo fi eeru fun eeru, yeepe fun yeepe lojo naa.
Ojo Aiku, Sannde, ojo kerinla, ni
isin idupe yoo waye nile ijosin naa bere ni aago mesan-an aaro.
No comments:
Post a Comment