Ose to n bo ni won yoo sinku Folasade Senfuye, iyawo oludasile ijo Ile isura Olorun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 2 April 2019

Ose to n bo ni won yoo sinku Folasade Senfuye, iyawo oludasile ijo Ile isura Olorun


 
Lojobo, Tosidee, ojo kokanla, osu yii ni ayeye isinku iyawo oludasile ijo Ile isura Olorun iyenTreasure House of God, Arabinrin Folashade Senfuye yoo bere.

Gege bi atejade ti Ogbeni Adeniyi Adeloye, to je oluranlowo nipa iroyin fun Pasito Adeseye Senfuye, fi sita lo ti so pe ojo merin ni won la sile fojo naa.

Isin aisun ni yoo koko waye lojobo, Tosidee, nile ijosin Treasure House of God, Quarry Road, Abeokuta, bere ni deede aago marun- un irole.

Isin pataki lati fi saponle oloogbe naa ni yoo waye lojo Eti, Furaide, ojo kejila nile- ijosin yii bakan naa, aago mesan an aaro ni isin naa yoo ti waye.

Leyin ti won ba pari isin naa tan ni won yoo loo fi eeru fun eeru, yeepe fun yeepe lojo naa.

Ojo Aiku, Sannde, ojo kerinla, ni isin idupe yoo waye nile ijosin naa bere ni aago mesan-an aaro.

No comments:

Post a Comment

Pages