Lonii- in ni komisanna tuntun ti won sese gbe wa si ipinle Ogun, Bashir Dabup Makama bere ise gege bi ipo ti won sese yan-an si.
Gege bi
atejade kan ti agbenuso fawon olopaa nipinle naa, Abimbola Oyeyemi, fi sita
losan-an yii lo ti so pe okunrin naa ti wa bere ise ni pereu.
Ileewe giga
yunifasiti Bayero niluu Kano ni okunrin naa ti kawe gboye imo ijinle nipa oselu
sayensi. Odun 1986 lo darapo mo ise olopaa. O si ti sise kaakiri eka awon ileese
olopaa lorileede yii.
Odun 2016 lo
ni igbega sipo komisanna ngba to loo dari won ni Benue, leyin naa ni won tun
gbe loo si Abuja, ko to di pe won gbe lo si ipinle Kwara, Ipinle Akwa- Ibom lo
wa, ti won fi gbe wa si ipinle Ogun.
No comments:
Post a Comment